Pakistan train fire: Iná ńlá ti pa ènìyàn 74

Àkọlé fídíò,

Àjọ́ òsìsẹ́ pàjáwìrì ní ó seése kí iye àwọn ènìyàn tó kù ju bẹ́ yẹn lọ nítorí ènìyàn ogójì ló farapa nínú iná náà.

O kere tan eniyan mẹtalelaadọrin lo ti papoda lẹyin ti ọkọ reluwe to n ná ilu Karachi si Rawalpindi gbina lorilẹede Pakistan.

Minisita fun ọrọ reluwe lorilẹede naa, Sheikh Rashid Ahmed sọ wi pe afẹfẹ gaasi ti awọn eniyan fi n se ounjẹ owuro lo bu gbamu, to si fa ijamba ina naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ibugbamu naa ṣe akoba fun ọkọ̀ to le ni mẹta.

Oríṣun àwòrán, Rescue1122

Awọn osisẹ pajawiri sọ wi pe ọpọlọpọ awọn eniyan to ku naa n gbiyanju lati sa kuro ninu ina lasiko ti ijamba ọhun waye.

Oríṣun àwòrán, Rescue1122

Wọn ni o seese ki iye awọn eniyan to ku ju bẹẹ lọ nitori eniyan ogoji lo farapa yannayanna ninu ina naa.

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé