Yahoo Boys: Àwọn ọmọ Yahoo tí kò dín ní igba ni yóò fojú ba ilé ẹjọ - EFCC

EFCC Chairman

Oríṣun àwòrán, @officialpagemagu

Àkọlé àwòrán,

Ibrahim Magu

Adele alaga ajọ to n ri si iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, Ibrahim Magu, ni o ti fi aidunnu rẹ han si iwa ti iya awọn afẹsunkan lori ọrọ jibiti lilu lori ayelujara ti a mọ si Yahoo Boys.

Magu ṣalaye ọrọ yii lọjọbọ ni ẹka ile iṣẹ naa ti o wa ni ilu Eko pe, awọn iya ọmọ wọnyii n gbiyanju lati da ẹgbẹ silẹ.

Nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ, o wi pe, pupọ awọn iya wọnyii lo n sọ wi pe, awọn fi ara mọ iṣẹ ti ọmọ wọn n ṣe nigba ti ko si ọkọ tabi ti ọkọ ti sa lọ fun wọn.

Alaga yii wa fi idi ọrọ rẹ mulẹ wi pe kii ṣe pe ajọ naa yoo fi panpẹ ọba mu wọn lasan ṣugbọn wọn tun maa ṣe alakalẹ ọna ti wọn yoo fi wulo lawujọ ti wọn yoo si sọ wọn di ọtun.

Magu ni pataki apero yii ni lati gbogun ti iwa ibajẹ ati lati dẹkun gbogbo iwa iluni ni jibiti ori ẹrọ ayelujara.

O wa ni ko din ni Igba awọn iru ọmọ bẹẹ ti wọn yoo foju ba ile ẹjọ.

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé