Lagos Government: Abániwálé gbọ́dọ̀ darapọ̀ mọ́ ètò tuntun Ìjọba Ìpínlẹ Eko.

Ile ni Ilu Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eto Ile Gbigbe

Ijọba Ipinlẹ Eko ti ṣalaye pe opin yoo de ba gbogbo iwa jibiti to rọ mọ wiwale kiri ni Ipinlẹ naa ti awọn eniyan n doju kọ latari iṣẹ ọwọ awọn abaniwale.

Ijọba wa tẹpẹlẹ mọ wi pe, ẹrọ igbalode ni wọn yoo maa lo lati wa ile ti o tẹ wọn lọrun ti ko si ni mu idamu lọwọ mọ.

Wọn ni nigba ti gbogbo eto ba ti to tan ni yoo fun ọpọ ara ilu lanfaani lati wa iru ile, tabi ilẹ ti wọn ba fẹ lati ori ẹrọ igbalode pẹlu ẹni to jẹ alakoso iru ile bẹẹ.

Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo Olu ṣalaye pe, iru eto bayii ni yoo ṣe anfaani fun ara ilu nitori pe, wahala ati jibiti ọrọ ile ti pọ ju.

Ninu ọrọ ti Ijọba Ipinlẹ naa fi ṣọwọ sita, o ni gbogbo awọn ti o ni ohun kan tabi meji lati fun awọn eniyan ni lati ni ẹrọ igbalode naa ti ko si ni awuruju ninu.

Ko din ni Ọrinlenigba awọn eniyan ti abaniwale kan lu ni jibiti lagbegbe Ketu -Alapere.

Bakan naa ni bii Oṣu kan sẹyin ni enikan lu Aadọrin eniyan ni jibiti ni Gbagada lori yara olojule marun.

Gẹgẹ bi Olubada mọnran Gomina naa lori ọrọ ile gbigbe,Arabinrin Toke Benson -Awoyinka ti wi pe, ọrọ yii jẹ Ijoba logun gidigidi ti ko si le maa wo iru ọrọ bẹẹ niran.

Ni ọjọ Isinmi, ẹka ajọ Ọlọpaa ṣafihan awọn marun un kan ti wọn fẹ lu ọkunrin kan ni jibiti owo ti o to Miliọnu Mẹrin abọ naira,

O wa ni asiko ti to lati ṣatunṣe si gbogbo kudiẹkudiẹ to wa ninu iru iṣẹ bẹẹ ni Ipinlẹ Eko.

Nigba ti o n ba ile iṣẹ BBC sọrọ ni ọjọbọ lo ti ṣalaye pe awọn abaniwale ati onile ni yoo sọ fun Ijọba pe ko si iwa makaruruu lọwọ wọn ti ayẹwo yoo si wa lori dukia wọn.

Ko ṣai mẹnu ba afikun owo ojiji ti wọn maa n fi si owo ile lẹyin ti ayalegbe ba ti san owo tan ti o si n fa idaaru fun ojulowo abaniwale.

Owo ojiji yii gan an ni Ijọba yoo boju to ti yoo si mu ifọkan balẹ ba ara ilu.

Ohun Mẹwa ti Ijọba Eko yoo ṣe lati dẹkun Jibiti lori ile gbigba lọwọ awọn abaniwale

  • Eto tuntun naa yoo bẹrẹ ni Oṣu Kejila
  • Ayalegbe ati Oluralẹ yoo kansi ẹrọ ayelujara naa lati mọ ojulowo abaniwale tabi talẹ.
  • Yoo naa irufẹ abaniwale tabi ralẹ ni Ẹgbẹrun lọna Aadọta naira lọdun lati forukọ silẹ.
  • Dandan ni fun ẹni ba fẹ jẹ abaniwale ni ilu Eko lati forukọ silẹ.
  • Ile ẹjọ yoo wa fun ẹnikẹni to ba lu jibiti lori iru ọrọ naa.
  • Fun anfaani awọn ayalegbe tabi olurale, Ijọba yoo ran wọn lọwọ lati gbe irufẹ oni makaruruu bẹ lọ ile ẹjọ.
  • Abaniwale ko ni le gba ju idamẹwa owo lọwọ ayalegbe tabi ida marundinlogun ti wọn ba jẹ meji nitori o lodi sofin.
Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Ilana Ijọba yii yoo ran ara ilu lọwọ lọpọlọpọ, sugbọn o ṣeeṣe ko ma tan gbogbo iṣoro naa lẹẹkan nitori ko din ni miliọnu mejilelogun awọn eniyan to wa nilu Eko.

Gbogbo awọn onile to maa n fipa mu ayalegbe lati san owo ọdun meji ni yoo foju ba ile ẹjọ nitori o lodi sofin, ọdun kan ni ofin ṣe alakalẹ rẹ.

O wa rọ gbogbo awọn eniyan ilu Eko lati lo anfaani yii nitori yoo ṣe iranlọwọ to pọ fun wọn lẹyinwa ọla.

Olubadamọnran naa wa wi pe oju opo ti Ijọba yoo mu silẹ yii maa wulo pupọ fun gbogbo olugbe Eko ti awọn abaniwale si ti n beere fun eto naa.

Eto yii fun Ijọba Ipinlẹ Eko ni ifọkanbalẹ pe yoo késẹ jari ti yoo si ṣe adinku ba gbogbo iwa jibiti.