Trafficking in Abuja: Ọkùnrin 15 ni mò ń ba sùn lọ́ọ̀jọ áti san owó ọ̀gá mi

ọkan ninu awon ti wan ko yọ
Àkọlé àwòrán,

Trafficking in Abuja: Ọkùnrin 15 ni mo ń ba sùn lọ́ọ̀jọ áti san owó ọ̀gá mi

Kí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógun maa bá ènìyàn mẹ́ẹ̀dọógun sùn lójóoójúmọ jẹ́ ǹkan to bani nínú jẹ́ gidi.

Èyí jẹ́ ǹkan ti Ngozi (eyí kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan) ń là kọjá lójoojúmọ fún ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ oṣù nínú ilé ìtúra kan ní agbègbè Lugbe l'Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.

Ngozi dí èrò ilé Aṣẹ́wó lẹ́yìn ti àládúgbọ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Anambra fí lọ̀ọ́ pé oun yóò ràn án lọ́wọ́ láti baa rí iṣẹ́ láti le san owó ilé-iwé rẹ̀ ti o ba lé wá si ilú Abuja.

"Ọ̀gá mi a sọ pé ki ń wọ síkẹ̀tì pélébé àti búláòsì kékeré lati lọ le ara mi si ojú pópó. Ọkùnrin mẹ́ẹ̀dógun ni mò ń ba sùn ti wọ́n a sì san ẹgbẹ̀rùn kan náìrà fún ọgá mí" èyí ni ọ̀rọ̀ Ngozi.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Ajọ NAPTIP ni ìdá àádọ́rin ninu ọgọ́rùn un obinrin bii ti Ngozi ni wọ́n ti fí n ṣe aṣẹ́wo láti ìpínlẹ kan sí òmíràn ni orílẹ̀-èdè Naijiria.

Ní ti Mercy (èyí kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan) náà jẹ́ ọkàn lárá wọ́n. O sọ fún BBC pé wọ́n tan oun wá si ilé aṣẹ́wo náà ni agbègbè Lugbe ni Abuja.

O ní lẹ́yin ti òun siṣẹ́ tan fún ọ̀pọ́ oṣù fun ọgá òun, ni oun wá gbìyànjú lọ́jọ́ kan lati sálọ sùgbọ́n ọ̀gá oun pada gbá òun mú, o si fi abẹ gé gbogbo ara oun yálayàla.

Àkọlé àwòrán,

Trafficking in Abuja: Ọkùnrin 15 ni mo ń ba sùn lọ́ọ̀jọ áti san owó ọ̀gá mi

Ilé Aṣẹ́wó pọ̀ bàbì ní agbègbè Lugbe ni Abuja

Àdúgbọ ti ilé Aṣẹwo yìí wa jẹ́ ibi kan ti àwọn òtòsì pọ sí jùlọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdúgbò náà kò ni ojú pópó kan gidi, síbẹ̀ àwọn ilé aṣéwo ti wọ́n fi páko kọ ló pọ̀ jùlọ.

BBC ṣe àbẹwo si ilé aṣéwo yìí níbi ti ọ̀pọ́ àwọn ọdọmọbinrin pẹ̀lu aṣọ pénpé pọ si jùlọ ti àwọn ọmọ ọkùnrin àdúgbo náà si n tú iná igbó mímú ni ita otẹ̀lí náà.

Àkọlé fídíò,

Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Akoroyin BBC náà ṣe bi ẹni pé oun ni àwọn ọmọbinrin kéèkèké ti oun fẹ́ mú wá si ibẹ̀.

Ẹni to ba pàde sàlàye fún akọroyin BBC pé ko kan lọ mu yàrá kan ko si lo mú ọmọ náà wá fún iṣẹ́ síṣe

O sọ́ fun akoroyin wa pé yóò maa san ẹgbẹ̀rún méèdógun náira lọ́sọọsẹ̀ fún owó yàrá.

O fi kun un pé ti ọmọ ti o n mú bọ ko ba ti dagbà to lọ́jọ́ ori, o ní láti maa pe ọjọ ori rẹ̀ ni ogun ọdun ati jù bẹ́ẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, BBC

Àkọlé àwòrán,

Iyara kan ninu ile aṣẹwo ni Lugbe Abuja

Wọ́n sàlàye fún akọròyìn wá pé, ọmọ to ba mu wá yoo maa san ẹgbẹ̀run mẹwàá sí ẹgbẹ̀run mẹ́ẹ̀dogun lójoojúmọ pàápàá jùlọ bi o ba ṣe le ṣiṣẹ́ si.

Ọ̀gá àgbà fun àjọ NAPTIP, Julie Okah-Donli sàlàyé fun BBC pé àwọn ọmọ kekeeke ti wọ́n ń lo fun àwọn iṣẹ́ ibi yìí ti pọ̀ gan ni orilẹ̀-èdè Naijiria.

"Níwọ̀n ìgbà ti àwọn tó ń lọ ilé aṣẹ́wo ba ti wà, àwọn ọmọ keekeeke náà ni wọ́n a maa lò."

Julie ni ajọ náà ti lọ kaakiri lati ka awọn ilé aṣẹ́wo ti wọ́n ti n lo àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ náà mọ ti àwọn si ti ti omiran pa ti àwọn si gbe ẹni to nii lọ si ile ẹjọ.

Donli ni Síbẹ̀ lẹ́yìn ti àwọn ti gbé wọ́n lọ si ilé ẹjọ, àwọn o sinmi láti maa ran àwọn ọmo ti wọn ko kúro nibẹ̀ lọ́wọ́, Ngozi àti Mercy pẹ̀lú àwọn ọmọ míràn ti ajọ náà gbà sílẹ̀ ni àwọn ti kó lọ si ibi ààbò kan ni ìlú Abuja nibi ti wọn ti n kọ́ iṣẹ́ ọwọ́.