Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Awọn oriṣa Brazil ló ni akara- Helgies

Adele aṣoju orilẹ-ede Brazil ni Naijiria, Helgies Bandeira gba BBC Yoruba lalejo ninu ọgba ileeṣẹ Brazil nilu Eko.

O ṣalaye kikun nipa ijọra awọn aṣa Yoruba ati ti orilẹ-ede Brazil.

Helgies ni awọn ti Brazil maa n ro pe aṣa Yoruba ni aṣa ti wọn naa ni Brazil.

O ni awọn naa n sin oriṣa bii Ogun, Ọṣun, Ọbatala, Yemoja atawọn mii.

Bakan naa ni Helgies sọrọ lori ounjẹ bii akara to jẹ tawọn oriṣa ati akarajẹ to jẹ tawọn eniyan.

Opọ ọmọ Yoruba ni wọn ko lọ si orilẹ-ede Brazil nipasẹ owo ẹru laye atijọ ni eyi ti ọpọ si ti di ero Brazil lati atọmọdọmọ wọn.