Seyi Makinde pàṣẹ kí wọ̀n dáwọ iṣẹ́ dúró lórí iṣẹ́ àgbàṣe ₦67bn òpópónà Ibadan Lagos Bye Pass

Aworan Seyi Makinde ni opopona ti wọn da iṣẹ duro lori rẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyiamakinde

Àkọlé àwòrán,

Gomina Seyi Makinde ko ṣẹṣẹ ma bẹnu atẹ lu iye owo agbaṣe nipinlẹ Oyo ti ijọba rẹ jogun

Ijọba ipinlẹ Oyo ti paṣẹ ki awọn agbaṣẹ to n ṣiṣẹ lori opopona Ibadan Circular road eleyi ti awọn awakọ le ma gba dipo oju ọna marosẹ Lagos Ibadan lati dawọ iṣẹ duro.

Gomina Seyi Makinde lo paṣẹ yi lasiko to n ṣe abẹwọ lati mọ bi iṣẹ ti ṣe n lọ si lọna naa.

Makinde ni lati ọdun 2017 ni wọn ti buwọlu iwe adehun iṣe agbaṣe ọna naa.

Makinde ni ijọba yoo ṣe ipade pẹlu awọn kọngila ti wọn gbe iṣẹ naa fun lati le mọ ọna tawọn yoo fi wa owo iṣẹ naa tori pe opopona ohun ṣe pataki si ọrọ aje ipinlẹ Oyo.

Kilomita mẹtalelọgbọn ni ọna naa jẹ ti wọn si ya biliọnu mejilelọgọta kalẹ fun iṣẹ rẹ.

Makinde sọ fawọn oniroyin pe ida marun un le diẹ ninu ida ọgọrun un iṣẹ naa ni wọn ṣẹṣẹ ṣe.

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyiamakinde

Àkọlé àwòrán,

Opopona ti wọn da iṣẹ duro lori rẹ la gbọ pe ida marun ninu ida ọgorun iṣẹ ni wọn ṣẹṣẹ ṣe

Ọrọ owo lori iye ti wọn ya fun iṣẹ naa ti n mu ki ẹnu maa kọ awọn eeyan lori iye naa.

Awọn kan to wi tẹnu wọn loju opo Twitter sọ pe iye owo yii ti pọju lati fi ṣe opopona naa.

Gomina Seyi Makinde ko ṣẹṣẹ ma bẹnu atẹ lu iye owo agbaṣe nipinlẹ Oyo ti ijọba rẹ jogun.

Laipẹ si igba to gun ori alefa lo sọ pe agbaṣẹṣe kankan ko gbọdo mu owo ẹyin wa ba ohun bi wọn ti ṣe n ṣe pẹlu ijọba to kọja.

Àkọlé fídíò,

Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil