Indonesia Adultery: Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ìjìyà ẹgba jíjẹ wà fún

Aworan ibi ti wọn ti n fi ijiya ẹgba jẹ Mukhlis Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Mukhlis to jẹ ẹni ọmọ ọdun mẹrindinlaadọta ni onimọ ẹsin akọkọ ti wọn yoo fi ijiya ẹgba jijẹ jẹ ni agbegbe Aceh,Indonesia.

Arakunrin ọmọ orileede Indonesia kan to kopa ninu bi wọn ti ṣe ṣagbekalẹ ofin ẹgba jijẹ fun iwa agbere ti faragbẹgba tori pe oun gan hu iwa agbere.

Ẹgba mejidinlọgbọn ni Mukhlis bin Muhammed to jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn Ulama Aceh(MPU) jẹ.

Obinrin to ṣagbere pẹlu rẹ naa la gbọ pe wọn na lẹgba mẹtalelogun.

Agbegbe Aceh nibi to ṣe pe oun nikan ni ibi ti awọn eeyan ti ma n tẹle ofin Sharia ni Mukhlis ti wa.

Iwa ibalopo laarin akọ si akọ tabi abo si abo to fi mọ tẹtẹ tita ta ko ofin nibẹ ti wọn si fi ijiya ẹgba jijẹ lélẹ̀ fawọn ẹṣẹ yii.

Husaini Wahab to jẹ igbakeji adari ilu agbegbe Aceh Besar ti Mukhlis n gbe sọ fun BBC Indonesia pe ''Ofin Ọlorun ni. Ẹni ti igba ofin ba ṣi mọ lori ti a si ri aridaju rẹ gbogbo a fara gbẹgba koda ko jẹ ọmọ ẹgbẹ MPU''.

Loṣu kẹsan ni awọn alaṣẹ lagbegbe naa ka wọn mọ ninu ọkọ kan nibi ti wọn ti n ṣe agbere.

Lọjọbọ ni wọn da sẹria ẹgba fun wọn ti ẹgbẹ MPU si sọ pe awọn yoo yọ Mukhlis kuro ninu ẹgbẹ awọn.

Mukhlis to jẹ onimọ nipa ẹsin ni akọkọ onimọ ẹsin ti wọn yoo dajọ ijiya ẹgba fun lati igba tofin naa ti fẹsẹ mulẹ lọdun 2005.

Related Topics