Operation Positive Identification: Ọnà àti dúnkokò mọ́ ará ìlú ni o

Aworan Yinka Odumakin ati Ọgagun Tukur Buratai Image copyright OTHER

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin ti bu ẹnu atẹ lu erongba ajọ Ologun nipa eto pe wọn yoo maa ṣayẹwo idanimọ awọn ọmọ Nigeria.

Olori ajọ awọn omo Ologun lorilẹede Nigeria, Ọgagun Tukur Buratai, lo ti kọkọ ṣalaye pe, ọranyan ni fun awọn ọmọ Nigeria lati ni ọna idanimọ.

Awọn Ologun sọ pe ilana yii wa lati kapa ikọ Boko Haram ti wọn ti wọle si orilẹede Nigeria ni.

Ṣugbọn, Yinka Odumakin sọ pe ọna ati dun koko mọ awọn ọmọ Nigeria ni.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, o tẹpẹlẹ mọ ọ pe, iṣẹ Ọlọpa ati ajọ to n ri si iwọlewọde ni lati beere fun idanimọ awọn araalu kii ṣe iṣẹ ajọ Ologun rara.

Odumakin wa rọ ara ilu lati ma ṣe ba ọkan jẹ rara pe, gbogbo ribaribo ti ijọba asiko yii n ti wọn fun, igba diẹ ni.

Ko ṣai mẹnu ba a wi pe, ẹni eegun n le, ko maa rọju, bo ṣe n rẹ ara aye naa lo n rẹ ara ọrun.

Ṣaaju ni ajọ ọmọ ologun ti kede pe ọjọ Ẹti ọsẹ yii ni wọn yoo bẹrẹ eto naa lẹyẹ- o- sọka, ti awọn ọmọ ile Igbimọ Aṣofin si ti pe fun ẹkunrẹrẹ ọna ti wọn yoo gbe e gba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil