'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wole Soyinka sọ ìdí tó fi ni òun a fi màálù Fulani ṣe súyà fáwọn èèyàn abúlé

Wole Soyinka: Fraternity táwa bẹ̀rẹ̀ ní ìtàn tirẹ̀ ṣùgbọ́n ...

Wole Soyinka: ìyàtọ̀ gedegbe wà láàrin ẹgbẹ́ Pirate Confraternity táwa dá sílẹ̀ lọ́dún 1952 àti ǹkan áwọn ọmọ ayé òde òní ń ṣe.

Apeja orukọ rẹ ni Akinwande Oluwole Babatunde Soyinka ṣugbọn ti gbogbo agbaye m si Wole Soyinka. Onkọwe, olukọ ewi ati olukọ arosọ.

Koda awọn oyinbo nla nla lẹ le fi mọ awọn aṣeyọri wọn ati ọpọlọpọ oye ti o ti gba laye - iyẹn ni pe lowe lowe la n lu ilu agidigbo...

"Titi di bi mo ṣe n sọrọ yii emi funra mi o mọ ọ gidi, ẹni ti Wole Soyinka jẹ" lèsì Ọjọgbọn fun BBC Yoruba nigba ti a ni ki o juwe ara rẹ.

Wole Soyinka ti a bi lọjọ kẹtala oṣu keje ọdun 1934 kii ṣe ọmọde mọ lonii ṣugbọn gbigba ami ẹyẹ gẹgẹ bi ọjọgbọn ko tii wọn lápó rẹ̀.

Nínú ìrìnàjò BBC Yorùbá sí ilé Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka nínú igbó kìjikìji tó múlé sí ni ilu Abeokuta tii ṣe ilu ibi rẹ gangan, omi pọ lamu ohun ti BBC Yoruba ba bọ.

Latẹnu ọna igbo ti ẹ o gba wọ ile baba lẹ o ti ro pe inu igbo irumọlẹ tẹẹ maa n ka ninu itan gan lẹ ti de yii ayafi bi ẹ ba wọle tan.

Ṣe latara awọn igi to wa labawọle igbo aginju ti ile rẹ wa ni ti awọn akọle awo bẹru wa.

Tabi awọn igbo kijikiji ati igi gogogro to yi ọgba ile ọjọgbọn ka.

Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ló fi pàṣẹ̀ àti ìkìlọ̀ fún màálù àtàwọn tó ń dà wọ̀n tó bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ wọn ò sì bí baba màálù kankan dáa.

Soyinka sọ ohun to difa fun akọle yii pe "igba ti awọn daran daran fẹ wa jọba le wa lori ninu ile ti mo kọ ni mo kọ akle naa mo si sọ fun baalẹ ati ọlọpaa agbegbe yii".

O ni oun dẹ sọ fun wọn pe maalu to ba wa lẹyin eleyii, ko fara mọ ohun toju ẹ ba ri. Tori naa mo ṣe kọ akọle sara igi pe, maalu to ba kọja aye rẹ o, aa sọ ọ di suya".

"Fraternity ní ìtàn tirẹ̀ ó dẹ̀ lápẹrẹ oríṣirísi ṣùgbọ́n ..."

Nipa itan ti ọpọlọpọ ma n sọ lori bi ẹgbẹ okunkun ṣe bẹrẹ lawọn ile iwe giga oni eyi ti wọ́n ma n lọ mọ ẹgbẹ "Pirate Fraternity" ti Wole Soyinka atawọn ọrẹ rẹ mẹfa kan da silẹ lọdun 1952.

Soyinka ni "ko yẹ keeyan tilẹ maa ronu lọ sibẹ rara tori ibanujẹ gbaa ni. Awọn ọmọ olowo, oniwakuwa, ti wọn o lẹkọọ lo da ẹgbẹ ti wọn ti wọn n pe ni "Fraternity".

Eyi lo ti wa di ẹgbẹ okunkun to n da awọn ile iwe giga ati igboro ru lode oni. Ọjọgbọn ni "àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn òde òní kàn ń ba orúkọ ẹgbẹ́ tí àwa dá sílẹ̀ ní 1952 jẹ́ ni".