Ní ọdún márùn-ún sí àsìkò yìí, mùṣùlùmí yóò pọ̀ ju Kristẹni lọ, ìjà ẹ̀sìn yóò sì wà - Primate Ayodele
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Primate Ayodele: Àwọn pásítọ̀ tó ń lo bàálù pẹ̀lú èrò rẹpẹtẹ ń tan aráàlú jẹ ni

Oluṣọaguntan agba Ayodele ni oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church ti a si mọ ọ fun ọpọlọpọ asọtẹlẹ lorilẹede Naijiria.

Bakan naa o ti di gbajugbaja lori ayelujara fun oniruuru ọrọ to ma n suyọ latari awọn asọtẹlẹ rẹ.

Primate Ayodele gẹgẹ bi gbogbo eeyan ṣe maa n pe ni awọn iran mii ti ojiṣẹ Ọlọrun ba sọ, bo ṣe ri kọ ni ẹlomiran ṣe ma n tumọ rẹ lo fi ma n da bii pe ko wa si imuṣẹ.

Ṣugbọn o ni gbogbo asọtẹlẹ ti oun ma n sọ maa wa ni akọsilẹ.

Bakan naa o jẹ ko di mimọ pe ijọba gan ko ṣe e dara tori bo ba ṣe nkan to nii ṣe pẹlu aṣa ni wọn lee kede isinmi ṣugbọn nkan ti Ọlọrun ni ijọba ko ki n fẹ kede isinmi fun.

O ni awọn pasitọ to n lọ tẹnu bọlẹ kiri lọdọ ijọba tabi oloṣelu n wa ohun ti wọn a jẹ kiri ni amọ oun o ki n ṣe eeyan bẹẹ́.