Nigeria vs Netherlands: Àtilẹ ló yẹ kí ìjọba ti máa mu ìdàgbàsókè bá eré bọ́ọ̀lù-Onigbinde

Idije FIFA U-17 Image copyright ALEXANDRE SCHNEIDER - FIFA

Gbajugbaja akọnimọọgba ere bọọlu ni Naijiria,Adegboye Onigbinde ti gba ajọ ti o n ri si ere bọọlu ni Naijiria, NFF ati ijọba apapọ niyanju lati maṣe da ikọ ọjẹwẹwẹ agababọọlu ilẹ naa nu.

Onigbinde sọrọ yii nigba ti o n fesi si ibeere ti ikọ ile iṣẹ BBC n beere pe kini igbesẹ to yẹ ki ijọba gbe lori ikọ Golden Eaglets lataari ijakulẹ wọn lọwọ Netherlands lọjọ Iṣẹgun.

Bi a ko ba gbagbe,awọn ọjẹ wẹwẹ naa ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun lọ ni wọn fidirẹmi ninu idije ife ẹyẹ agbaye U-17 to n lọ lọwọ ni Brazil.

Ami ayo mẹta si meji ni Netherlands fi juwe ọna ile fun ikọ naa .

Onigbinde ṣalaye pe, ki ẹka to n ri si eto ere boolu gbiyanju lati tẹpẹlẹ mọ igbaradi awọn ọdọ wọnyii ki wọn le tunbọ ni oye ati imọ sii.

O tẹnumọ pe o ṣe pataki lati mu idagbasoke ba awọn ọdọ naa ki wọn si maa mu wọn gbaradi fun ayeye miran fọjọ iwaju.

O ni atilẹ lo yẹ ki ijọba ati ẹka yii ti maa ran awọn ọjẹ wẹwẹ lọwọ lati mura silẹ kii ṣe igba ti wọn ba ni idije kan pato.

O tọka si pe, ọpọ awọn orilẹede to n ṣe daada ni wọn gunle iru igbesẹ bayii ti wọn si n ṣe daada ni gbogbo asiko ti wọn ba ti idije.

Ẹgbẹ agbabọọlu ọjẹ wẹwẹ orilẹ-ede Naijiria, Golden Eaglet ko r'ohun mu bọ láti Brazil nibi ti wọn ti lọ fun idije FIFA U-17.

Eyi ni onipele ikẹrindinlogun idiije awọn agbabọọlu tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun lọ lagbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJawahir Roble:Hijab tí mò n lò kó jẹ́ kọ́kọ́ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn agbábọ́ọ̀lù mi

Ami ayo mẹta si ookan ni ẹgbẹ agbabọọlu ọjẹ wẹwẹ orilẹ-ede Netherlands fi ṣe wọn bọṣẹ ṣe n ṣoju, ni wọn ba di ẹru wọn pada wale.

Atamatase ọwọ iwaju ikọ Netherlands, Sontje Hansen lo gba goolu mẹtẹẹta ọhun s'awọn Naijiria, ni wọn ba sọ Naijiria di a lọ ma lee pada wa mọ bi wọn ti ṣe ninu ifẹsẹwọnsẹ meji kan sẹyin.

Nile ti Naijiria, Olakunle Olusegun lo jẹ goolu kan ṣoṣo ti wọn ri jẹ.

Olakunle ti jẹ olugbade fun igba marun un bayii ninu idije naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'