'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Art Exhibition: Ṣé ẹ láwọn ọ̀dọ́ kò mọ Àṣà ni, ẹ wo itú t'ọ́mọ ọdún mẹ́rìndílógún kan ń pa

Gbigbe aṣa Yoruba larugẹ ti di ohun to n jẹ awọn ọmọ kaarọ o jiire logun bayii to bẹẹ tawọn ọdọ ko gbẹyin.

Bi ala awọn baba nla Yoruba ṣe ti wa n ṣẹ naa lo n mu ki awọn eniyan maa mu ọpọlọpọ ọgbọn ati gbe aṣa Yoruba ga jade.

'Màálù tó bá tàsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ níwájú ilé mi, ó dẹran àsun!"

Nibi akanṣe eto ṣiṣe afihan iṣẹ ọna ka to waye l'Eko, awọn ọdọ lo wọ pọ nibẹ to fi mọ ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan ati awọn obinrin ti BBC Yoruba ba sọrọ.

Kii wọpọ ki awọn obinrin maa yọra sibi iru nkan bayii ṣugbọn wọn pọ ti wọn patẹ iṣẹ ọwọ wọn lọtẹ yii.

Related Topics