Balogun Market Fire: Àwọn òǹtàjà gbarata lórí òfò tí ìjàmbá ìná ń mú báwọn lọdọọ́dún

Awọn ontaja kan lọja Balogun ti n di ẹbi ina to jo ru ẹni to ni ibudo itaja alaja mẹfa ti ina naa ti sẹyọ pe, aibikita rẹ lo mu ki ọwọja ina ọhun fẹju ju bo se yẹ lọ.

Ọkan lara awọn ontaja naa, Busayọ Ọlalere, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni awọn kesi ẹni to ni sọọbu naa pe ina n jo, to si ni ki awọn fi ina naa silẹ, yoo ku funra rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olalere ni ọdọọdun abi ọdun meji sira wọn ni ina maa n jo sọọbu naa, eyi ti ko se ajeji si awọn ara ọja Balogun amọ o ni ko ba dara ki obinrin naa ti tete pa ina naa ko to burẹkẹ, eyi ti ko ni ko wahala ba awọn eeyan yoku to wa ninu ọja.

Ina to n jo nile itaja lọja Balogun

"O ti yẹ ki onisọọbu ti ina jo tete lo awọn eroja panapana ki ọwọja ina naa to fẹju, ni bayii, ina ọhun ti mu ọpọ isọ, to si ti ko ba awa ta mule ti wọn. O nira fun wa lati ko ẹru wa jade nitori eefin to n bo wa mọlẹ."

Ọlalere fikun pe "ọja to jona kọja biliọnu lọna irinwo naira, ati igba ti iya to n ta asọ ti ra ile alaja mẹfa to jona naa, lo maa n jona lopin ọdun, to si mọ pe awọn eeyan yoo ta ọja ọdun."

Awọn panapana si n pa ina to n jo

O ni obinrin naa n fi tiẹ se akoba fun awọn eeyan miran nitori bi ina se maa n jona lọdọọdun, ti a ko si mọ boya wọn yoo tun ibudo itaja naa kọ abi bẹẹ kọ, to si tun rọ ijọba lati pasẹ fun obinrin naa pe ko maa ra awọn eroja to n pa ina si ibudo itaja rẹ, lati tete maa pa ina.

Nigba toun naa n kin Busayọ Ọlalere lẹyin, Alhaji Kehinde Ajikanle naa fikun pe o yẹ kijọba se iwadi lori idi to se jẹ pe inu ibudo itaja Adebọwale Plaza nikan ni ina ti maa n sẹyọ lọja Balogun lọdọọdun.

Awọn ero to n daro ofo to waye tori ijamba ina

Ajikanle ni lootọ ni ontaja asọ naa padanu awọn ọja ti owo wọn to aimoye biliọnu naira, nitori oun nikan lo n lo ibudo itaja alaja mẹfa naa, ti ọja si kun inu wọn dẹnu amọ o ni awọn eeyan to mule ti ibudo itaja naa lo maa n faragba.

Sanwo-Olu sabẹwo si ọja Balogun to jona

Wayi o, isẹlẹ ina to n waye lọja Balogun nilu Eko ti di irawọ ọsan, to n ba awọn agbaagba lẹru bayii, ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu si ti sabẹwo si ibudo naa lọjọru.

Babajide Sanwo-Olu sabẹwo si ọja Balogun to jona Image copyright Other

Lasiko to de ibi isẹlẹ naa, awọn irinsẹ ajọ panapana si n sisẹ lọwọ lati ko awọn awoku ile to jona naa, ti wọn si tun n wọn omi si awọn agbegbe ti eefin ti n ru jade titi di ọsan oni.

Lasiko abẹwo rẹ si ni Sanwo-Olu ti pasẹ pe ki wọn se ayẹwo awọn ile to wa lẹba ile to jona naa lati mọ boya ki wọn da awọn ile ọhun wo pẹlu eyi to jona abi ki wọn fi silẹ.

Gomina wa rọ awọn eeyan to n ta asọ lọja Balogun lati maa sọra se nibi ti isẹlẹ naa ti waye nitori ina ọhun si n ru eefin bi o tilẹ jẹ pe wọn ko ti mọ ohun to sokunfa ina ọhun.

Ina mii tun sẹyọ ni ọja Balogun

Ijamba ina lọja Balogun Image copyright OTHER

Ina miiran ti ṣẹyọ ni ibudo itaja ti ina ti jo lana, ni ipinlẹ Eko.

Bi ẹ ko ba gbabe, lana ode yii ni ina kan dede ṣeyọ lọja ọhun ti ọpọlọpọ dukia ati ọja si ba ina ọhun lọ.

Gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ agbofinro Rapid Response Squad ipinlẹ Eko fi lede loju opo Twitter rẹ, ẹmi ọlọpa kan ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Ọga Olọpaa kan ni Ipinlẹ Eko, Bode Ọjajuni ṣalaye pe, Ọlọpaa naa ni ile wolu mọlẹ ni bi ti o tin gbiyanju lati le awọn eniyan sẹyin ni bi iṣẹlẹ naa.

O ni ẹnu iṣẹ ni arakunrin naa ti o jẹ sajẹnti Ọlọpaa ku si ninu igbiyanju rẹ si awọn eniyan awujọ

Awọn oṣoju mi koro sọ pe ina tuntun yii ṣeyọ lowuro oni, ni bi aago mẹfa kọja iṣẹju diẹ.

Wọn ni o jọ pe ajọ panapana ko pari iṣẹ wọn lati pa ina naa lana, nitori ina to ṣeyọ lowurọ yii wa lati ile to fẹgbẹkẹgbẹ ile to jona lana ni.

Awọn oṣoju mi koro ọhun ṣalaye pe o ṣeṣe ko jẹ pe ajoku ina to ṣẹyọ lana lo jo wọ ile keji.

Awọn ajọ panapana ti wa ni ojuko iṣẹlẹ ọhun lati dẹkun ina naa, lati le daabo bo awọn ile miran to wa layika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'