Gomina Fayemi: Dayo Adeyeye sì ń padà bọ̀ wá ṣèjọba

Aworan Seneto Adeyey ati Seneto Olujimi Image copyright OfficialPDPNig

Gomina Ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti sọ wi pe yiyọ ti ile ẹjọ yọ Agbẹnusọ fun Ile Igbimọ Asofin, Dayọ Adeyeye kuro ni Ile Igbimọ Asofin.

Eyi ko sẹyin bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣe dajo wi pe sẹnẹtọ Biodun Olujinmi ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ni ẹni to wọle idibo sile aṣofin agba fẹkun idibo Guusu Ekiti, kii ṣe Adeyeye.

Fayemi ṣapejuwe Adeyeye ti wọn ye aga mọ ni idi oun gẹgẹ bi ojulowo oloṣelu to mo iyi iṣejọba awaarawa.

O fikun un wi pe idajọ naa kii se opin irinajo Sẹnetọ Adeyeye, ati wi pe yoo dide pada laipẹ.

Bakan naa ni Gomina Fayemi wa ki Seneto Olujimi ku oriire, ati wi pe oun setan lati sisẹ papọ pẹlu asofin naa fun itẹsiwaju ipinlẹ Ekiti.

Olujimi ló borí ìbò fẹ́kùn gúúṣù Ekiti, Adeyeye gba ile lọ - Iléejọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ṣèdájọ́

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to fi ilu Kaduna ṣe ibujoko ti dajọ pe, Sẹnẹtọ Biodun Olujimi ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ni ẹni to wọle idibo sile asofin agba fẹkun idibo guusu Ekiti.

Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Gomina Fayemi: Dayo Adeyeye sì ń pada bọ̀ wá ṣèjọba

Ohun ti eyi tumọ si ni pe, aga ti yẹ bayi nidi Ṣẹnẹtọ Dayo Adeyeye ti ẹgbẹ All Progressives Congress APC, to jẹ agbẹnusọ ile aṣofin agba ni Abuja.

Saaju ni ajọ eleto idibo Naijiria INEC ti kede, Dayo Adeyeye gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo to waye ni agbegbe naa ṣugbọn Olujinmi tako esi ọhun niwaju igbimọ to n gbẹjọ idibo.

Image copyright Others

Loju opo Twitter ẹgbẹ oṣelu PDP, wọn fi iṣẹ ikinni ku oriire ranṣẹ si Ṣẹnẹtọ Olujimi lori bi ile ẹjọ kotẹmilọrun se kede pe oun lo jawe olubori ibo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPrepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà