Seyi Makinde: N kò ní yẹ ìdí àkóso aya Ajimobi wò lórí ọ̀rọ̀ SACA, ohun tó kọjá ti kọjá

Seyi Makinde ati aya rẹ Image copyright @seyimakinde

Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ti ṣe ifilọlẹ igbimọ alakoso tuntun fun ajọ to n bojuto didẹkun ọwọja arun Aids ati kokoro rẹ, SACA, to si yan aya rẹ, Tamunominini Makinde gẹgẹ bi alaga igbimọ naa.

Gomina Makinde fikun pe ajọ SACA naa ni aya gomina ana, Florence Ajimọbi jẹ alaga rẹ tẹlẹ, amọ o ni ọpọ ninu awọn alẹnulọrọ ti n gba oun niyanju lati ṣe iwadii isakoso aya Ajimobi naa ninu ajọ Saca.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ Makinde ni oun ko ni ṣe iwadi aya gomina ana naa nitori ohun to kọja ti kọja lọ.

Gomina ipinlẹ Ọyọ ni lootọ ni iwadi ti sisọ loju rẹ pe, ilana ti igbimọ alakoso ajọ Saca to kọja, labẹ aya Ajimobi n lo, ni rira awọn oogun ti ọjọ ti fẹ lọ lori wọn,

O wa rọ awọn ọmọ igbimọ alakoso tuntun fun ajọ Saca lati ta kete si iwa kiko oogun pamọ amọ ki wọn sisẹ fun rere awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.

Image copyright @seyimakinde

Gomina, ẹni to kede pe agbega ti n ba ipese oogun iwosan fun arun Aids, tun woye pe ọna to pegede julọ lati ka ọwọja itankalẹ arun Aids ko ni tita kete si ibalopọ ti ko tọ.

"Ipese eto ilera to yanranti jẹ ara opo ti isejba mi rọgbọku le lori, bẹẹ si ni isẹ kikọju oro si itankalẹ arun Aids ati kokoro rẹ lawujọ wa jẹ ohun to se pataki julọ si ijọba yii."

Image copyright @seyimakinde

"Mo ti lo ọpọ akoko lati se asaro lori ilana ti wọn gba dari ajọ Saca tẹlẹ, mo si lee fi gbogbo ẹnu sọ pe awọn oogun to ku diẹ ki ọjọ lọ lori wọn ni wọn n ra. Wọn ti ko diẹ lara awọn oogun naa wa han mi, amọ akoko naa ti kọja lọ, ti ko si ni waye mọ lailai nipinlẹ Ọyọ."

Gomina Makinde wa fọwọ gbaya pe ko si aniani pe awọn eeyan to kaato ni yoo maa se akoso ọrọ Aids nipinlẹ Ọyọ .