Ṣé ó yẹ́ kí èèyàn sanwó iná tí wọn kò bá fún un ní mítà?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Prepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà

Ọrọ to n lọ bayii- ọrọ lori mita ina mọnamọna!

Ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria ti ko si ni ọpọlọpọ awọn agbegbe ati owo gọbọi ti wọn n mu wa fara ilu ni wakati perete to ba fi wa lo n kọ ọpọ eeyan lominu lasiko yii.

Ọrọ to n lọ jẹ eto akanṣe ti BBC Yoruba a fi maa gba ẹdun ọkan awọn eniyan lori koko to ba n dùn wọn lọkan.

Ọpọ ọmọ Naijiria fi ibanujẹ wọn han lori ina ọba ti kii si ati owo to ga ju agbara lọ ti awọn oniṣẹ mọnamọna n muwa fun wọn loṣooṣu.

Bi awọn kan ṣe ni ko yẹ ki ki awọn eniyan maa sanwo gọbọi lori mita ti wọn n ka lẹyin tijọba ti ni ki wọn pin mita oniwiwọn fun odiwọn ina ti onikaluku ba lo;

Bẹẹ naa ni awọn miran ni ki ijọba ṣi maa fun wọn ni biili afojusun ṣugbọn ko ma ga ju ara lọ.

Ni ipari, Felix Ofulue to jẹ aṣoju ileeṣẹ ina mọnamọna ni Ikeja ni ipinlẹ Eko di ẹbi ọrọ yii ru alakalẹ ijọba lori ina pinpin to pọju paapaa lori mita piripeedi.

O gba awọn eeyan nimọran pe ko tọna lati má sanwo ina ti wọn n lo rara.