Cultural Burial: Ìdí táwọn ènìyàn South Korea ṣe ń sin èèyàn láàyè!

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idi pataki ni pe onikaluku gbadun igbe aye rẹ nitori pe aye la maa kọkọ ṣe ki a to ṣe ọrun!

O le ni eto isinku eniyan ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn ti ile isinku Hyowon Healing Centre ti ṣe fawọn eniyan lààyè!

Igbesẹ akọkọ fun ilana eto isinku awọn eniyan ti wọn ṣi wa laaye ti wọn ko tii ku ni pe ẹni naa a kọkọ ṣe akọsilẹ iwe ipingun rẹ to ṣafihan bo ṣe fẹ ki wọn pin ogun oun.

Lẹyin eyi o maa sanwo to yẹ nile isinku to wuu lati ṣeto isinku rẹ nigba ti ọlọjọ ba de.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPrepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà

Orilẹ-ede South Korea ni aṣa yii ti wọpọ julọ.

Iru ẹni bẹẹ maa tun ra irufẹ posi to wuu ki wọn fi sin oun si lẹyin to ba papoda.

O maa wa sun sinu posi yii fun nkan bii iṣẹju mẹwaa o kere tan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Choi Jin-Kyu to jẹ akẹkọọ to ṣẹṣẹ pe ọmọ ọdun mejidinlọgbọn to ti kopa ninu eto isinku alaaye yii ṣalaye fawọn akọroyin pe oun ṣee nitori pe gbogbo eeyan n ṣee ni.

Choi ni pe oun ṣẹ nitori oun maa to bẹrẹ iṣẹ ati pe oun fẹ ki ọkan oun balẹ pe oun ti ṣe nkan to yẹ ni ṣiṣe.

Ojọgbọn Yu Eun-sil to jẹ dokita to n ṣayẹwo iku to pa eniyan ni o ṣe pataki fawọn ọdọ lati mọ sii nipa iku ki wọn si ṣeto to yẹ.

Ojọgbọn yii to ti kọ iwe loriṣiirisi nipa iku ẹda ni ko si ohun to buru ninu ki eeyan musilẹ de ọjọ iku rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBalogun Fire: Àwọn èèyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣàlàyé ohun tó fa iná lọ́jà Balogun

Ogbeni Jeong Yong-mun to ni ileeṣẹ Hyowon ni inu oun maa n dun ti awọn eniyan ba n forijin oku ṣugbọn o san lati foirjin ara wọn nigba ti ẹni naa ba ṣi wa laaye nitori o ti le pẹ ju nigba mii lẹyin iku.

O tun ni igbese yii maa n yi ero awọn miran ti wọn ronu lati pa ara wọn pada si daadaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'