Maina Court Case - A sún ìgbéjọ síwájú láti mọ ipò tí ìlera rẹ̀ wà

Abdulrasheed Maina Image copyright Others

Adajọ Okon Abang ile ejọ giga tijọba apapọ ti sun igbẹjọ Abdulraheed Maina si ọjọ kọkanlelogun ati ikejilelogun oṣu Kọkanla ọdun 2019 lati mọ ipo ti ilera ara olujẹjọ naa wa.

Adajọ Abang wa pasẹ fun ileesẹ to n samojuto ọgba ẹwọn lati lọ ṣe iwadii ipo ti ilera Maina wa ni tootọ nitori bo ṣe wọ ile ẹjọ pẹlu kẹkẹ ni ọjọbọ.

Abang ti sọ saaju pe iwe idajọ oun lori ibeere Maina lati gba oniduro rẹ ni ko ti si nilẹ.

Adajọ ileejọ giga naa ni ọpọlọpọ iṣẹ to wa ni iwaju ile ẹjọ naa ni ko jẹ ki iwe naa wa nilẹ, ti oun yoo fi gbe asẹ kalẹ lori gbigba oniduro Maina.

O fikun pe oun yoo fi ọjọ miran ti oun yoo gbe asẹ naa kalẹ ransẹ si igun tọrọ kan ko to di opin akoko isẹ lọjọ Iṣẹgun.

Lẹyin eyi ni adajọ wa tẹti gbọ awijare lati ọdọ awọn agbẹjọro olupẹjọ ati olujẹjọ lori boya ki igbẹjọ naa tẹsiwaju abi bẹẹ kọ nitori ipo ailera ti olujẹjọ naa wa.

Olupẹjọ sọ fun ileejọ lati sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kọkanlelogun ati ikejilelogun oṣu Kọkanla lati fun ileesẹ to n se akoso ọgba ẹwọn ni aaye fun iwadi ipo ti ilera Maina wa gangan, igbesẹ naa si waye nitori iwe abọ ayẹwo ilera to mu wa sileẹjọ.

Amọ igun olupẹjọ salaye pe ti ile ẹjọ ko ba ṣetan lati gba ẹbẹ pe ki wọn sun igbẹjọ naa siwaju, oun ṣetan lati tẹsiwaju pẹlu ẹjọ naa, niwọn igba ti ẹlẹri rẹ akọkọ si wa ni ile ẹjọ.

Adajọ Abang ba sun igbẹjọ naa siwaju si ọjọ kọkanlelogun ati ikejilelogun oṣu Kọkanla ọdun 2019.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Abdulrasheed Maina de sile ẹjọ giga ni

Maina dé sílé ẹjọ́ nínu 'Wheel Chair' láti wa jẹ́jọ́ rẹ̀

Saaju la ti mu iroyin wa pe ile ẹjọ giga ni olu ilu Naijiria, Abuja n gbọ ẹjọ Abdulrasheed Maina to jẹ alaga ajọ to n risi ọrọ owo ifẹyinti awọn eniyan.

Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn meji lo ti Maina wọle sinu ile ẹjọ ni aarọ yii.

Igbagbọ awọn eniyan ni pe ileẹjọ a da ẹjọ lori gbigba oniduro rẹ loni ọjọbọ.

Adajo Okon Abang lo mu oni lati fi ṣeto idajọ gbigba oni iduro Maina bi o ṣe pe ẹjọ naa.

Ẹsun mejila lori ṣiṣe owo ilu ni mọkumọku ni ajọ EFCC to n gbogun tiwa ibajẹ ni Naijiria fi kan Maina.

Bakan naa ni Maina n jẹjọ lori ileeṣẹ Common Input Properties and Investment Limited ti wọn fẹsun kan pe o niiṣe pẹlu iwa jibiti.

Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ni Kuje ni ilu Abuja ni wọn ti Maina wọle lori kẹkẹ fawọn ti ko le rin ni nkan bii agogo mẹsan an abọ aarọ yii.

BBC Yoruba yoo maa gbe gbogbo bo ba ṣe n lọ fun un yin!

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPrepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà