Balogun market fire: Olubadamọran gomina sọrọ lori ina náà

A ko ni akiyesi ina ni Naijiria bii tawọn eeyan ilẹ oke okun- Kehinde Ajikande

Lẹyin ti ọja Balogun tun jona ni ipinlẹ Eko ni awọn oniṣowo loriṣiirisi ti n fi ero ọkan wọn han lori iṣẹlẹ naa.

Oriṣii ọna ni awọn eeyan mii n gba tumọ iṣẹlẹ ọja jijona naa ti wọn lo maa n ṣẹlẹ lọdọọdun.

Ọpọ gba awọn oniṣowo ninu ọja yii lo ti ni ki ijọba wadii iṣẹlẹ ina naa bo ti yẹ ki iru rẹ le dopin.

Wọn tun sọrọ lori adanu nla ti awọn ọlọja n koju gegẹ bii ipenija wọn.

Olanrewaju Elegushi to jẹ olubadamọran fun gomina Sanwo Olu to n tukọ ipinlẹ eko ṣalaye pe asiko ti to ki ijọba ati ara ilu tubọ maa fiyesi iṣẹlẹ ina ojiji.

Igbiyanju BBC lati ba awọn ti ọrọ kan lori ọrọ aajo aje yii sọrọ ja si pabo.