Adigunjalè ń bèérè ẹyin, ouńjẹ ati aṣọ lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ń jà lólè ní ìpinlẹ Niger

Aisha, to jẹ olugbe ijọba ibilẹ Rafi, ni ipinlẹ Niger
Àkọlé àwòrán Aisha sọ fun BBC pe dukia ti oun fi ọpọ ọdun ko jọ ni awọn adigunjale ọhun ko lọ

Ninu ibẹru bojo ni awọn olugbe ijọba ibilẹ Rafi, ni ipinlẹ Niger n gbe bi wọn ṣe ni kosi aabo fun wọn lati ọdọ ijọba.

Awọn eniyan Kompani Madaka n bẹru latari bi awọn adigunjale ṣe n kọlu wọn ni gbogbo igba.

Laipẹ yii ni awọn adigunjale wọ agbegbe naa ti wọn si n bere owo, ẹyin, ounjẹ ati aṣọ lọwọ awọn ti wọn n ja lole.

Ọpọ ohun ini awọn eniyan yii ni awọn ole ti fibọn gba lọ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ni oun ti ran awọn alabo ilu sagbegbe ọhun, sugbọn awọn eeyan naa ni ko si ohun to jọ bẹ.

Àkọlé àwòrán Gbogob ounje inu aka won ni awon ole ti ko lo tan

Awọn eeyan ọhun sọ fun BBC pe, awọn adigiunjale naa maa n kora wọn si ori alupupu, ti wọn si maa n pin ara wọn si ọna marun un, ki wọn to ṣọṣẹ.

Àkọlé àwòrán Isaac ni ninu iberubojo ni gbogbo awon n gbe bayii

Adamu Shehu to jẹ ọkan lara awọn olugbe ọhun ni, ọpọ awọn eeyan agbegbe naa lo jẹ alaini.

O ni gbogbo ere oko ti wọn ko pamọ sinu aka wọn ni ole ti ko lọ tan.

Adamu ni, ninu ọṣẹ ti awọn ole ọhun ṣe kẹyin ni wọn ti ji maluu marun un, agutan ogoji, ati ẹrọ ibanisọrọ ogoji.

O ni ko si nkan ti wọn ko ki n bere fun ti wọn ba ti de tibọntibọn si abule awọn.

Àkọlé àwòrán Hassan: Gbogob ewure wa ni won ti ko lo tan

Olugbe agbegbe ọhun miran sọ fun BBC pe inu oun bajẹ gidi nitori awọn eeyan naa maa n kopa ninu idibo, ṣugbọn wọn ko jẹ anfani kankan lara ijọba.

Hassan ni bi wọn ṣe n gab ounjẹ ti awọn ti se silẹ ni wọn n gba ounjẹ tutu ti wọn ko tii

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPrepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà

Bayii, awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria ti bẹre iṣẹ akanṣe lọjọbọ ti wọn pe ni Operation Cat Race lati fi gbogun ti awọn agbebọn.

Wọn ni iṣẹ akanṣe yii maa wa titi di osu kejila ni ṣugbon nigba ti Akoroyin BBC de abule yii, ko ri agbofinro kankan nibẹ lasiko naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBalogun market fire: Olubadamọran gomina sọrọ lori ina náà