Ibadan Circular Road- Ilé aṣòfin ní ìṣẹ́ 5.5% ni agbaṣẹ́ṣe ṣe lọ́nà olóbìrípo láti 2017

Makinde n ba agbasẹse sọrọ Image copyright Oyo state government
Àkọlé àwòrán Ibadan Circular Road - Ilé aṣòfin Ọyọ ní ìṣẹ́ 5.5% ni agbaṣẹ́ṣe ṣe lọ́nà olóbìrípo láti 2017

Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Oyo ti kesi ileesẹ ENL Consortium, ti wọn gbe isẹ lila opopona olobiripo ti yoo yi Ibadan ka, taa mọ si Circular Road le lọwọ, lati wa sọ tẹnu rẹ lori idi to fi pinnu lati gbe gomina Seyi Makinde lọ sile ẹjọ.

Ile Aṣofin ni igbesẹ lati kesi ileesẹ ọhun jẹ eyi ti o dara julọ, eyi ti yoo tan imọlẹ si ohun to ṣokunkun lori iṣẹ agbaseto n la oju ọna olobiripo Ibadan naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn Aṣofin ipinlẹ Ọyọ fi ohun ṣọkan bẹẹ nibi ijoko wọn to waye lọjọbọ, ti wọn si woye pe igbesẹ ileesẹ ENL Consortium lati gbe ijọba Ọyọ lọ sile ẹjọ nilu London jẹ eyi to lee kan awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ labuku ati ijọba Naijiria pẹlu.

Image copyright Oyo state government

Bẹẹ ba gbagbe, ijọba Abiọla Ajimọbi lo gbe isẹ lila oju ọna olobiripo oni kilomita mejilelọgbọn naa fun ileesẹ agbasẹ́se yii, ni biliọnu mẹtadinlaadọrin naira.

Amọ ileesẹ naa binu nigba ti ijọba Ọyọ fẹsun kan an pe o gbe owo gun isẹ agbase ọhun lati biliọnu mẹrinla si mẹtadinlaadọrin naira, to si ni oun yoo pe ijọba lẹjọ nilẹ Gẹẹsi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Gẹgẹ bi Aṣofin Adeola Bamidele, ti o n ṣoju ẹkun idibo Iseyin/itesiwaju sọ pe, o yẹ ki Agbaṣẹṣe naa gboriyin fun Ijọba ni dipo ko maa dunkooko mọ nitori ida marun un ni ipele ti iṣẹ oju ọna naa de lati bii ọdun meji abọ sẹyin, ti ko si fi han pe ile iṣe naa fẹ tan iṣoro ti awọn eniyan n koju.

Image copyright @oyoassemblytweeter
Àkọlé àwòrán Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Oyo

O ni, iṣẹ naa lo kọkọ dawọ duro nibẹrẹ pẹpẹ nitori ọpọ nkan lo dabi eyi ti ko tọ lori isẹ naa, bẹrẹ lori iye ti iṣẹ naa jẹ dori boya ile iṣẹ naa to gbangba n sun lọyẹ.

Wayi o, gomina Seyi Makinde ti wa paṣẹ pe ki ile iṣẹ naa pari iṣẹ lila opopona olobiripo ọhun titi oṣu karun ọdun 2020 gẹgẹ bi o ti wa ninu iwe ajọsọ awọn mejeeji lojuna ati mu idẹrun ba tolori tẹlẹmu ni Ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPrepaid Meter: èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí 'sisan owó iná ní Nàìjíríà

Olori ile Aṣofin, Adebo Ogundoyin ṣalaye pe, o jẹ ohun ti o bani ninu jẹ pelu bi ile iṣẹ naa, ENL ti n dun koko mọ ijọba lẹyin ipade ajọṣepọ pe ki wọn o pada sẹnu iṣẹ.

Image copyright Oyo state government

Gẹgẹ bi Abẹnugọ naa ti wi, o ni kilo buru ninu ki wọn o beere idi ti agbaṣẹṣe ko se ti i pari iṣẹ ọdun mẹta to gba lati ọdun 2017, ti ko si ti ṣe ju ida mẹwa ni ọdun 2019, ki o si wa ṣalaye fun ara ilu.

Abẹnugọ ni, alaga ile iṣẹ naa, Clement Haastrup ti ṣetan lati fọ ara rẹ mọ kuro lara awọn ti o ṣe orilẹ ede yii baṣubaṣu.

O wa ni fun ilọsiwaju awọn eniyan, ara ilu ati Ipinlẹ Oyo, Ile fẹnu ko lati pe ile iṣẹ naa wa lati wa tan imọlẹ si okunkun ti o wa lori ọrọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'