Illegal Rehab Centre: Feb 2008 ni wọ́n fẹ̀ṣùn kan Olore pé ó pa èèyàn 60 nígbèkùn

Awọn eeyan ti wọn mu nigbekun nile Ọlọrẹ Image copyright Seyi Makinde

Laipẹ yii ni iroyin tan kalẹ pe ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ tun ti se awari ibudo miran ti wọn ti n mu awọn eeyan si igbekun eyi to n fi iya jẹ wọn.

Gẹgẹ bi iroyin naa se wi, o to awọn eeyan bii igba ti ori ko yọ ninu ile ọhun ti wọn n pe ni ile Ọlọrẹ, ẹni to jẹ agba Aafa nilu Ibadan.

Lati igba ti isẹlẹ naa ti waye, ni ẹsẹ ko ti gba ero nibi ti ile naa wa, tijọba ipinlẹ Ọyọ si ti ko awọn eeyan ti wọn mu si igbekun ninu ile Ọlọrẹ naa lọ si ibomiran fun itọju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa nijọba ni ki wọn wo ile ọhun nitori iwa ifiyajẹni to n waye nibẹ.

Amọ iwadi BBC Yoruba fihan pe kii se igba akọkọ niyi ti akara yoo tu sepo nipa iwa aidaa to n waye nile Ọlọrẹ nitori irufẹ isẹlẹ yii naa tun waye losu keji lọdun 2008.

Image copyright Other

Ileesẹ ọlọpa yii kan naa lo se awari isẹlẹ awọn eeyan to le ni ọgọta ti wọn fi iya jẹ titi de oju iku , ti wọn si sin wọn sibẹ lai jẹ ki ọrọ naa lu sita.

Iroyin naa ni se ni wọn kan nipa fun awọn eeyan ti wọn n fiya jẹ, to wa nigbekun ninu ile naa lati maa fi tipa jẹ ẹran oku awọn akẹẹgbẹ wọn to ku lasiko ifiyajẹni.

Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpa ti salaye nigba naa, o to awọn eeyan bii mejilelaadọrun ti wọn tu silẹ nigbekun nile Ọlọrẹ naa, ti akoko ti awọn eeyan si fi wa nigbekun ninu ile ọhun si wa laarin ọjọ mẹta si ọdun meje.

Image copyright Other

Bakan naa ni wọn mu awọn afurasi mọkanla lọdun naa ninu ile Ọlọrẹ, to fi mọ oludasilẹ ibudo naa, Alfa Mohammed Ọlọrẹ.

Nigba to n salaye ohun ti wọn n se nibẹ nigba naa, Alfa Ọlọrẹ ni o ti le ni ọdun mẹjọ ti ohun ti da ibudo naa silẹ, ijiya ẹsẹ eyikeyi awọn eeyan to ba sẹ nibẹ si lee gba to igba pankẹrẹ.

Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Ọyọ nigba naa, Udom Ekpoudom salaye pe ikọ to n gbogun ti iwa idigunjale nileesẹ ọlọpaa lo lọ sile Ọlọrẹ naa, ti asiri ohun to n waye nibẹ fi tu.

Amọ Alfa Ọlọrẹ wa ṣẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan nigba naa.