Fasola: Àwọn ọmọ Nàíjíríà kojú oro sí Fasola lórí bó ṣe ní ọ̀nà kò fi bẹ́ẹ̀ bàjẹ́

Oju ọna ti ko dara Image copyright @Maryhanoh

Ọgọọrọ awọn ọmọ Naijiria lo ti n faraya loju opo ikansi ẹni Twitter fun minita fọrọ ilegbe ati eto irinna, Babatunde Raji Fasola lori ọrọ to sọ.

Fasọla lo kede lọjọru pe awọn opopona to wa lorilẹede Naijiria ko buru to bawọn araalu se n pariwo.

Fasọla ẹni to kede ọrọ naa lẹyin ipade igbimọ alasẹ ijọba tun fikun pe, asọdun lasan ni awọn ọmọ Naijiria n se pe awọn opopona to wa nilẹ yii ti di pakute iku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Niwọn igba to jẹ pe isọrọ ni igbesi, Asoju-sofin kan, Salam to n soju ẹkun idibo Ẹdẹ/Ẹgbẹdọrẹ/Ejigbo lo kọkọ fesi pada fun Fasola pe ki oun ati awọn alasẹ yoku kẹyin si wiwọ baalu fun osu kan, ki wọn si gbe ọkọ yika Naijiria lati mọ bi awsn oju popo wa ti bajẹ to.

Image copyright @nafeezi

Bakan naa, nigba ti wọn n fun Fasola lesi pada lori gbolohun to ti ẹnu rẹ jade ọhun, awọn ọmọ Naijiria loju opo Twitter ni ko ba dara ki minisita naa jawọ ninu apọn ti ko yọ, ko si da omi ila kana tori oselu ti tan.

@nafeezi n tiẹ se afihan awọn ọna kan to ti bajẹ faraye.

@112teejay ni iriri to ba ni ninu jẹ ati eyi to doju tini ni oun ri lasiko ti oun rin lati Enugu ls si Lọkọja de Ajaokuta.

@dark_lawyergirl ni iya nla ni ọkọ oun n jẹ loju popo, yoo si dara ki minisita naa dakẹ.

@AdekaunsiTemi1 ni ọrọ ti minisita naa sọ soro lati gbagbọ, yoo si dara ki minisita naa wo fidio ti oun n safihan rẹ lori Twitter.

@AyanfeOfGod ni o dabi ẹnipe orilẹ-ede Naijiria miran ni awọn alasẹ wa n pe eyi to yatọ si tawọn ọmọ Naijiria.