A ó gbé àjọ DSS lọ ilé ẹjọ́ tí wọ́n bá kọ̀ láti tú Sowore sílẹ̀ - Falana

Image copyright @_ShattaBandle
Àkọlé àwòrán A ó pe àjọ DSS lẹjọ́ tí wọ́n bá kọ̀ láti tú Sowore sílẹ̀ - Falana

Odindin wakati mẹrin ni awọn agbẹjọro wa lo fi n duro de ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lanaa- Falana.

Ṣaaju ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti kọkọ sọrọ pe ko sẹni to wa lati gba Soworẹ ati Bakara kuro ni ahamọ awọn lọjọ Ẹti.

Wọn fi atẹjade sita pe nitootọ lawọn gba iwe lati ile ẹjọ pe ki wọn tu Sowore ati Bakare silẹ, ṣugbọn ko si ẹni tó wa gbaa silẹ ni akata awọn.

Ati pe awọn ti fi to ilẹ ẹjọ leti pe ko sẹni to tii wa gba sowore lọwọ awọn ati pe awọn ṣetan lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ.

Ajọ DSS ni awọn maa n tẹle ofin ile ẹjọ ṣugbọn Falana ni irọ ni nitori awọn agbẹjọro n duro lati gba Sowore ati Bakare nibẹ.

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

A ó pe àjọ DSS lẹjọ́ tí wọ́n bá kọ̀ láti tú Sowore sílẹ̀ - Falana

Agbẹjọro fun Omoyele Sowore, Femi Falana ti sọ pe oun yoo pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS, lẹjọ latari bi wọn ṣe tẹsiwaju lati fi onibara rẹ re, satimọle lẹyin ti ile ẹjọ ni ki wọn da silẹ.

Image copyright @chekpointchaley
Àkọlé àwòrán Ofin orilẹ-ede Naijiria ko faye gba pe ki wọn gbe eeyan sẹwọn, lai ṣe pe ile ẹjọ paṣẹ bẹẹ

Falana lo sọrọ yii ninu ifẹorọwerọ kan pẹlu BBC.

O ni "Ko si ẹni to lagbara ju ile ẹjọ lọ, bẹẹ ni ko si ẹni to le ṣe ohun to wu labẹ ofin ilẹ Naijiria."

Falana ṣalaye pe ofin orilẹ-ede Naijiria ko faye gba pe ki wọn gbe eeyan sẹwọn, lai ṣe pe ile ẹjọ paṣẹ bẹẹ.

O ṣalaye siwaju sii pe awọn agbẹjọro Sowore yoo kọ iwe si ile ẹjọ, latari bi ajọ DSS ṣe kọti ikun si aṣẹ ile ẹjọ lati tu silẹ.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Sowore ṣì wà ni àgọ́ àwọn DSS lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́

Agbẹjọro agba ọhun wa sọ siwaju si pe, ti ajọ DSS ba kọ lati tu Sowore silẹ, oun yoo pe ọga agba ajọ ọhun lẹjọ.

O ni oun yoo pem igbẹjọ lati mu ki ajọ DSS san owogbab mabinu fun gbogbo ọjọ ti Sowore lo latimọle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra

Ṣaaju asiko yii:

Sowore ṣì wà ni àgọ́ àwọn DSS lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Sowore ṣì wà ni àgọ́ àwọn DSS lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́

Omoyẹle Soworẹ to dije dupo aarẹ Naijiria loṣu keji, ọdun 2019 yii lo ṣi wa lakata awọn DSS ni abuja titi di isinyii.

Olawale Bakare ati Omoyele Sowore ni ajọ DSS ko ṣi tii fi silẹ lẹyin ti Adajọ Ijeoma Ojukwu ti ile ẹjọ giga ni Abuja ti fọwọsi itusilẹ wọn.

Lọjọru ọsẹ yii ni Adajọ Ijeoma ti ni ki wọn tu soworẹ silẹ kuro ni akata awọn ajọ DSS.

Marshal Abubakar to jẹ agbẹjọro Sowore Omoyel ni aago mẹwaa aarọ ọjọbọ ni ileẹjọ mu iwe itusilẹ naa fun wọn.

O ni lẹyin eyi ni wọn sọ fun oun pe awọn yoo kàn sí wọn to ba ya.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBalogun Fire: Àwọn èèyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣàlàyé ohun tó fa iná lọ́jà Balogun

Ajọ DSS mu oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters ati Bakare ni o din diẹ ni ọgọrun un ọjọ sẹyin.

Lẹyin igbiyanju iwọde #Revolution Now ni wọn fi ẹsun kan wọn pe wọn fẹ doju ijọba bolẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa ni Adajọ Ijeoma gba oniduro awọn mejeeji ni eyi ti wọn ko tete ri ọna abayọ si awọn gbendeke gbigba oniduro wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Bayii, Adajọ Ijeoma ti tun gbendeke oniduro Sowore ati Bakare yẹ wo ni eyi ti awọn mejeeji si ti ri ojutuu si bayii.