Boko Haram: Ọmọ ogun Nàìjíríà méjìlá dàwátì lẹ́yìn ìkọlù Boko Haram

Ọmọ ogun ilẹ Naijiria Image copyright @Uduakkende
Àkọlé àwòrán Lati ọdun 2018 ni lemọ lemọ awọn ẹgbẹ Boko Haram si awọn ọmọ ologun Naijiria ti n peleke sii

Iroyin kan lati ọdọ ajọ ologun orilẹ-ede Naijiria sọ pe awọn ọmọ ologun mẹwaa ti jẹ Ọlọrun nipe lẹyin ikọlu ikọ Boko Haram ni Domba, ni ipinlẹ Bornu.

Ẹnikan ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe, ajọ ọhun si n wa awọn ọmọ ogun mejila lẹyin ikọlu naa lọjọru ọsẹ yii.

O ni "Awọn ọmọ ogun mẹwaa la padanu ninu ija pẹlu ẹgbẹ Boko Haram ni igba ti wọn da wa lọna".

O so siwaju sii pe "ọmọ ogun mẹsan an ṣeṣe, a ko si mọ ibi ti awọn mejila wa."

Ẹgbẹ Boko Haram ṣe akọlu sawọn ọmọ ogun naa nigba ti wọn bọ lopopona Damboa, to jẹ ibusọ mejidinlaadọrun un si Maiduguri.

Ninu akọlu ọhun ni alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram ti dana sun ọkọ ologun Naijiria, ti wọn si tun ji awọn ohun ija oloro ko lọ.

Image copyright @Army
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ ogun n foju wina Boko Haram ni ariwa Naijiria

Lati ọdun 2018 ni lemọ lemọ awọn agbesunmọmi Boko Haram si awọn ọmọ ologun Naijiria ti n peleke sii, leyi to jẹ pe ẹgbẹ Islamic State ti iwọ orun Afirika naa ko gbẹyin ninu awọn akọlu naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra