Oyo Budget: Kọmisánà fétò ìṣúná ní ìmúṣẹ ìlérí Seyi Makinde ni ìṣúná ọdún 2020

Gomina Seyi Makinde atawọn ara ipinlẹ Oyo Image copyright Twitter/Seyi Makinde

Igbesẹ ipade itagbangba lori aba eto isuna ọdun 2020 nipinlẹ Ọyọ jẹ ọna gbogi lati mu ileri ti ijọba Gomina Ṣeyi Makinde ṣe wi pe ijọba yoo maa ṣeto pẹlu ifọwọsọwọpọ ati ajọṣiṣẹpọ awọn araalu.

Kọmiṣọna feto iṣuna ati aato ọrọ aje nipinlẹ Oyo, Amofin Adeniyi Farinto lo ṣalaye bẹẹ lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ, pẹlu afikun pe, anfaani wa sọ tẹnu rẹ ti ijọba fawọn araalu lori eto iṣuna yoo jẹ ki ijọba mọ ni pato ohun ti ilu kọọkan nilo.

Farintọ woye pe, ilana yii yoo ran ijọba lọwọ lati rii wi pe ilu to ba fẹ ipese omi, ijọba ko ni ṣe titi sibẹ ati bẹẹbẹẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmiṣọna feto iṣuna tẹsiwaju pe ijọba gbe eto yii lati jẹki gbogbo eeyan ipinlẹ Oyo ati awujọ agbaye rii pe, ilana iṣuna ọdun 2020 nipinlẹ Oyo kii ṣe ọrọ idakọnkọ.

Image copyright Adeniyi Farinto

Ọgbẹni Farintọ ni "ijọba ni lati pada lọ sọdọ awọn eeyan lati beere ohun ti wọn fẹ lẹyin ti wọn ti dibo fun ijọba to wa lori aleefa bayii.''

Bakan naa, akọwe agba nileesẹ eto iṣuna nipinlẹ Oyo, Foluke Adebiyi sọ pe, igbesẹ ijọba lori eto iṣuna ọdun 2020 yoo fun awọn araalu lohun ninu eto iṣejọba ipinlẹ Oyo, eyi ti ko ri bẹ tẹlẹ.

Image copyright Seyi Makinde

Adebiyi ni eto yii to jẹ akọkọ iru ẹ ninu itan ipinlẹ Oyo, yoo mu aye dẹrun fawọn eeyan ipinlẹ naa.

Iyaafin Adebiyi ni iru eto yii lawọn ijọba kaakiri agbaye maa n ṣe lati fun awọn eeyan ti wọn dibo yan wọn lohun.

Ìlàná ìṣúná tí yóò mú aráàlú kúrò nínú àìní bọ́ sí ọ̀pọ̀ là fẹ́ gbékalẹ̀ - Seyi Makinde

Saaju ni ipade itagbangba lori aba eto isuna ọdun 2020 ti gberasọ lẹkun idibo guusu Ọyọ, ninu ọgba UCH nilu Ibadan.

Afojusun ipade naa ni lati bun awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ gbọ nipa aba isuna ọdun 2020, ki wọn si se akojọpọ ero awọn araalu nipa ohun ti wọn n poungbẹ, ti yoo si wọ inu aba naa.

Nigba to n sọrọ nibi ipade ita gbangba akọkọ to waye fẹkun idibo guusu Ọyọ, ni gbọngan nla to wa loọgba iwosan UCH nilu Ibadan, gomina Seyi Makinde salaye pe ọna lati se agbekalẹ eto isuna ti yoo ba aini awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ pade lo sokunfa ipade ọhun.

Image copyright Seyi Makinde

"Lati ọdun mọdun ni ariyanjiyan ti maa n waye lori ọna to dara julọ lati sejọba, se ilana ki ijọba maa gbe ilana afojusun kalẹ faraalu ni, ti yoo si fọ si wẹwẹ fun amusẹ abi ki araalu maa se ojuse nidi agbekalẹ afojusun, to si ni ilana mejeeji lawọn se amulo rẹ."

Bakan naa lo fikun pe oun ko se agbeyẹwo ilana isuna ọdun 2019 lati tabuku ẹnikẹni amọ oun sakiyesi pe ipinlẹ Ọyọ n se kọja agbara rẹ ni, ti wọn ko si samulo ofin bi ọwọ eku ba se mọ lo fi n họri.

Image copyright Seyi Makinde

Saaju ninu ọrọ rẹ, Kọmisana feto isuna ati aato ọrọ aje, Amofin Adeniyi Farintọ ni ipade itagbangba ọhun lo n fidi rẹ mulẹ pe ijọba alajumọse lo wa nipinlẹ Ọyọ bayii, to si setan lati ko awọn araalu kuro nipo osi bọ si idẹrun.

Farintọ ni irufẹ ipade itagbangba yii ni yoo pese anfaani lati sagbeyẹwo oniruuru ero fun idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ Ọyọ.

Image copyright Seyi Makinde

Ipade ita gbangba fun awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ naa ni yoo si waye lẹkun idibo apapọ mẹtẹẹta to wa nipinlẹ naa.