Ìtàn Mánigbàgbé: Ṣango gbèrò ibi fún Gbọnka àti Timi, àmọ́ òun gan bá ọ̀tẹ̀ náà lọ

Timi Agbale Ọlọfa ina n ta ọfa rẹ Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ìtàn Mánigbàgbé: Ṣango gbèrò ibi fún Gbọnka àti Timi, àmọ́ òun gan bá ọ̀tẹ̀ náà lọ

Ẹlẹdaa fi ọpọ awọn akọni nla jinki ilẹ Yoruba laye atijọ.

Awọn naa ni arogun matidi, abawọnja ma se ojo, awọn ti ilu ṣee gbọkanle, iru wọn si ni Timi Agbale Ọlafa ina ati Gbọnka Ebiri.

Timi Agbale ati Gbọnka Ebiri jẹ akọni ọdẹ aperin ati jagunjagun ni Ọyọ atijọ, ti wọn ko si lee kọ iyan wọn, ki wọn ma fi ewe boo, ti itan si sọ fun wa pe Timi lo da ilu Ẹdẹ, to wa nipinlẹ Ọṣun silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ baa se kaa loju opo itakun agbaye, taa si rii gbọ ninu itan atẹnudẹnu, a lee tọpasẹ itan Gbọnka ati Timi Agbale si ọdun 1500.

Eyi jẹ lasiko to n lo ọfa to maa n yọ ina lati fi ja ogun, idi si niyi ti wọn ṣe n pe e ni Timi Agbale Ọlọfa ina.

Gbọnka Ebiri ni tiẹ kii lo ọfa lati jagun amọ o ni oogun ju Arọni lọ, eyi to maa n lo lati fi sẹgun ọta.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ẹlẹdaa fi ọpọ awọn akọni nla jinki ilẹ Yoruba laye atijọ.

Itan naa sọ fun wa pe, Timi Agbale jẹ ọrẹ timọ-timọ fun Gbọnka Ebiri, ti awọn mejeeji si jẹ jagunjagun laye igba ti Alaafin Sango n jọba.

Bi itan igbe aye Timi Agbale Ọlọfa ina ati Gbọnka Ebiri se lọ ree:

 • Apetan orukọ Timi Agbale ni Timi Kubọlajẹ Agbọnran, ti orukọ baba rẹ si n jẹ Lalẹmọ. Awọn ọmọ baba rẹ ni Oyefi, Ajẹnju, Arohanran ati Oduniyi
 • Timi Agbale bi ọmọkunrin meji amọ ti itan ko sọ ohunkohun fun wa nipa Gbọnka Ebiri.
 • Timi Agbale ati ọrẹ rẹ, Gbọnka Ebiri jẹ alagbara nla ni Ọyọ ile, to si de akoko kan ti agbara Alaafin Sango ko fẹ ka wọn mọ, ti ẹru si n ba a pe awọn mejeeji le pa oun tabi le oun kuro lori itẹ.
 • Idi ree ti Alaafin Sango fi n wa ọna lati ya ọrẹ korikosun mejeeji naa, to si ni ki wọn ran Timi Agbale to buru julọ laarin awọn mejeeji nisẹ iku ti ko ni lee pada de mọ.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'
 • Eyi lo mu ki Alaafin Sango ran Timi Agbale lati lọ dena de awọn agbesunmọmi to wa lati ilẹ Ijẹsa laarin ilu Arà ati Awó, pẹlu igbagbọ pe wọn yoo pa a nibẹ.
 • Timi Agbale ko fura pe isẹ iku ni Ọba ran oun, to si lọ lai se awawi kankan pẹlu awọn ọmọ ogun rẹ, to si lọ tẹdo si abẹ igi kan ti wọn n pe ni Ẹdẹ, eyi to wa laarin ilu Arà ati Awó. Ilu naa si la n pe ni ilu Ẹdẹ, eyi to wa titi di oni oloni
 • Asiko ti Timi Agbale wa nibudo yii ni alaafia jọba lagbegbe naa, ti awọn agbesunmọmi ko si wa da agbegbe naa laamu mọ, eyi to mu ko ransẹ si Alaafin Sango pe se oun lee maa pada bọ wale
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra
 • Alaafin Sango ni ki Timi Agbale duro si agbegbe naa, to si tun fọwọsi i pe ko maa gba owo ẹyọ marun un bii owo ibode lawọn agbegbe yii, ko si maa mu isakọlẹ wa fun oun.
 • Timi Agbale n fi isakọlẹ ransẹ si Alaafin Sango fun igba diẹ, nigba to ya, lo ba faake kọri pe oun ko ni fi isakọlẹ kankan ransẹ mọ si Alaafin.
 • Eyi to mu ki Ọba gbe onisẹ kan dide, Tọbalagbọ, lati lọ wadii ohun to mu ki Timi dawọ sisan isakọlẹ duro.
 • Timi sọ fun onisẹ Alaafin pe oun ti faake kọri lati san isakọlẹ fun Alaafin, to si ran wọn pada silu Ọyọ lọwọ ofo, ti isẹlẹ naa si bọ si apo ibinu Ọba
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo itan omi gbigbona ati tutu ni Ikọgosi Ekiti
 • Alaafin Sango wa ran ikọ ọmọogun kekere kan lọ kọlu Timi ni Ede, ko lee mọ pe Ọba ba lori ohun gbogbo amọ ajẹkun iya ni awọn onisẹ Alaafin jẹ, ti Timi si lu wọn bi ẹni lu bara.
 • Ojuti nla ni eyi jẹ fun ori ade naa, to si ro pe o seese ki Timi, ti wọn n pe ni Ẹlẹdẹ nigba naa wa doju ijọba oun bolẹ laipẹ.
 • Idi ni yii to fi ronu pe ẹnikansoso to lee ge iyẹ apa Timi ni ọrẹ minu rẹ, Gbọnka Ebiri nitori ole nii mọ ẹsẹ ole tọ lori apata.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele
 • Alaafin Sango sọ iwa orikunkun ti Timi Agbale hu si i fun Gbọnka, to si ni ko lọ mu u wa silu Ọyọ; amọ se ni Ọba pe awọn ọmọogun to n tẹle Gbọnka lọ si Ẹdẹ sẹyin, to si pasẹ pé wọn gbọdọ ri i daju pe wọn pa a eyi ti ko han si Gbọnka funra rẹ.
 • Awọn ọmọ ogun ọrẹ korikosun wọya ija, ti apa Timi si n lewaju, eyi to mu ki awọn ọmọ ogun Gbọnka sa sẹyin fun igba meji, lẹyin o rẹyin, wọn pinnu pe awọn olori ogun mejeeji ni ki wọn koju ija sira wọn, kawọn lee mọ ẹni ti yoo sẹgun
 • Gbọnka, gẹgẹ bii jagunjagun to ni oogun, pasẹ pe ki Timi sun lọ fọnfọn lasiko ija naa, to si di i tọwọ tẹsẹ lọ silu Ọyọ. Alaafin Sango ki i ku ogun ajaye amọ isẹlẹ naa ko dun mọ ọ ninu rara, to si pe awọn Ọyọmesi rẹ lati fun un ni imọran lori ohun to yẹ ko se lati rẹyin awọn jagunjagun alagbara mejeeji.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde
 • Awọn Ọyọmesi gba Alaafin Sango nimọran pe ko tako ija ti awọn ọrẹ meji naa ja ni Ẹdẹ, ko si pasẹ pe ki wọn tun ija naa ja nilu Ọyọ niwaju Ọba ati awọn Ọyọmesi
 • Ọjọ Akẹsan ni wọn tun ti fija pẹẹta, Timi ta ọfa rẹ, to si tase Gbọnka, ti onitọun naa si lo oogun lati fi mu ki Timi sunlọ fọnfọn, to si bẹ ori rẹ.

Ẹ̀ wo bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú etí òkun ṣe ń ṣiṣẹ́ l'Eko

World water day: Ẹrin Ijesa, Ọ̀ṣun Oṣogbo, àwọn ibùdó ìgbafẹ́ omi tí ó yẹ kí o mọ̀

Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa D.O Fágúnwà?

Afárá odo ọya keji :Ta ni yóò parí rẹ?

 • Bi Timi Agbale Ọlọfa Ina se jade laye ree, ti inu ọrẹ rẹ ko si dun si isẹlẹ naa rara, eyi to mu ko ransẹ si Alaafin Sango pe ko fi ori apere silẹ tabi ko ṣí igba wo, eyi to tumọ si pe ko ku nitori iku to n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni.
 • Gbọnka sọ fun Alaafin pe ko si agbara kankan to le le oun kuro nilu Ọyọ, ti Ọba ba si fẹ mọ bi irọ ni ọrọ naa abi tootọ, ko da ina nla kan silẹ, ko si pasẹ pe ki wọn gbe oun sinu rẹ
 • Inu Ọba dun si imọran naa, to si ṣe bẹẹ gẹẹ.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLagos King: Mátikú ọba tó lo lo ọdun mẹta lórí oyé latari rogbodiyan Eko
 • Bi wọn se ju Gbọnka sinu ina lo jona di eeru patapata, ti Alaafin si n fo fayọ pe oun ri ẹyin ọta oun mejeeji, amọ oju ẹsẹ ni Gbọnka jade pe oun ko ku, to si pasẹ pe Alaafin Sango pe ko se bi ọkunrin.
 • Ọba wa ri pe ko si abuja miran lẹyin ọpẹ mọ, idi ree to fi wọlẹ lọ, ti wọn si n bọ Alaafin Sango ni ọrọọrun, taa mọ si ọjọ marun marun, ta mọ si ọjọ Jakuta.
 • Lẹyin o rẹyin, ko sẹni to mọ ohun to sẹlẹ si Gbọnka mọ, ti oun naa si pada di ara ilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: