Ijebu: Ikú àbúrò mi ló ṣún mi dé ìdí orin kíkọ

Ijebu ati Ọdunlade Adekọla Image copyright Ijebu

Gbajugbaja osere tiata, Ọlatayọ Amokade ti gbogbo eeyan mọ si Ijẹbu, ti salaye lori iha ti idile rẹ kọ si isẹ to n se.

Ijẹbu, lasiko to n kopa lori eto ifọrọwanilẹnuwo lori BBC Yoruba salaye pe, inu iyawo oun kii dun si eebu ti akẹẹgbẹ oun, Ọdunlade Adekọla maa n bu oun lasiko ti awọn ba n sere tiata.

Ijẹbu ni bi o tilẹ jẹ pe eebu naa ko ni itumọ kankan si oun nitori ere lasan ni, amọ iyawo oun ko fi bẹẹ nifẹ si iru iwa bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye ohun to gbe de idi isẹ tiata, Amokade salaye pe lati kekere ni oun ti nifẹ si ere itage amọ oun kọkọ lọ sile iwe gbogbonse Poly Ibadan na, lati kẹkọ imọ nipa ibaraẹnisọrọ, taa mọ si Mass Communication, ki oun to gbajumọ isẹ tiata ni sansan.

Image copyright Ijebu

Ilumọọka osere tiata naa, ẹni to kede pe o ti to ọdun mẹẹdogun ti oun ti bẹrẹ isẹ ere tiata, ti aye si n fẹ oun, wa yan pe Muyiwa Ademọla, ti gbogbo eeyan mọ si Muyiwa Authentic, ni ọga to kọ oun lere tiata.

Ijẹbu, tii se ọmọ bibi ilu Ilisan Rẹmọ fikun pe yatọ si ere tiata, oun tun nifẹ si orin kikọ, to si jẹ pe orin kikọ gan ni oun fi bẹrẹ ere tiata bi o tilẹ jẹ pe oun ko yan isẹ orin laayo lati fi jẹun bii ere itage sise.

Image copyright Ijebu Instagram

O tẹsiwaju pe iku aburo oun kan ni oun fi bẹrẹ orin kikọ, ti oun si maa n kọrin fun ọmọ aburo oun naa to fi silẹ saye lọ pe oun dupẹ pe oun ri aanu gba.

Ijẹbu, to saba maa n ko ipa adẹrinposonu ninu ere tiata, tun salaye iha ti awọn eeyan kan kọ si ihuwasi oun se afọmọ rẹ pe, irọ to jinna sootọ ni pe oun ni igberaga nitori onirẹlẹ pọhunbele ni oun.

Amọ ko sai yan pe ipo ti eeyan ba wa ni yoo sọ iru iwa ti yoo hu sita, eyi to lee mu kawọn eeyan kan fi oju rere abi abuku wo onitọun, ti yoo si yun se atọna irufẹ iwa ti eeyan yoo hu lasiko naa.