Lagos Fire: Ọ̀pọ̀ èèyàn tó nílé ní àárọ̀, ní kò nílé mọ́ ní alẹ́ tórí iná tó jó ilé ní Okobaba

Awọn ọdọ lagbegbe Okobaba ko duro ki awọn osisẹ panapana de, ti wn fi n bu omi pa ina naa.

Haa! rẹrẹ run ni isọ pako ni Okobaba. Haa, aje o

Aje ooo! Ọlọrun yoo fi ofo ra ẹmi fun awọn ti ajalu naa deba.

Ẹnikan lo mọ ni ọrọ ina to jo ni isọ pako ladugbo Okobaba, nkan se

Ile aye, ile asan. Ọpọ eeyan to jẹ onile laarọ lo di alainile lori mọ ni ọsan gangan, afi ki Ọ́lọrun tu wọn ninu

Gbogbo dukia ti ina ọhun fi ọwọ ba lo jona di eeru

Awọn waya ina alagbara ree to ja silẹ nitori ijamba ina. A fi ki wọn tete palẹ rẹ mọ nilẹ ko ma baa se okunfa ijamba miran lagbegbe Okobaba

Ko kuku ni tan ninu igba osun, ka ma fi pa ọmọ lara. Diẹ lara awọn pako to jona ku ree. Ọlọrun yoo da igba rere pada fawọn onisowo pako ni Okobaba