Ketu Market Violence: Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ nigba táwọn òǹtàjà kọjú ìjà sí àjọ Task Force

Awọn ọdọ Image copyright Other

Rogbodiyan bẹ silẹ lọja Ketu lọjọ Ẹti nigba ti awọn oṣiṣẹ ajọ to ri si iwa ibajẹ ni ipinlẹ Eko, Task Force yabo ọja Jakande.

A gbọ ni pe ajọ Task Force naa pẹlu awọn ọlọpaa fẹ fi ipa le awọn to gbọja silẹ, ki awọn ọlọja naa to tako wọn.

Lẹyin naa ni a gbọ pe ọlọpaa yinbọn eyi ti ọta rẹ ba ọkan lara awọn olugbe adugbo Ketu.

Bayii ni awọn ọlọpaa kọju ija sawọn ọlọpaa ti ọrọ si di bọọlọ o ya n mi lọja naa.

Iroyin sọ pe, awọn ọdọ fi ibinu bẹrẹ si ni dana sun ọkọ loju popo, to fi mọ ọkọ akero BRT.

A gbọ pe awọn ọlọpaa ti lọ si agbegbe naa lati rii pe alaafia pada jọba ni agbegbe naa.

Ọkan lara awọn ọlọpaa to wa nibẹ ṣalaye pe, wọn ti gbe ẹni ti ọta ibọn ba lọsi ile iwosan, ẹmi ko si tii bọ lẹnu rẹ.