Ajọ FRSC ṣèlérí láti fọwọ́ òfín mu eegun tó bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ lásìkò ọdún Keresi

eegun Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ara ọrun to ba dena soju popo rogo lasiko ọdun Keresimesi to m bọ yii

Ajọ to n risi ẹṣọ oju popo, Federal Road Safety Commission ti kede pe wọn maa mu eegun ki eegun to ba jade lasiko ọdun keresimesi to ba dẹ fa sunkere fa kẹrẹ ọkọ.

FRSC fi eyi lede pe awọn ti woye pe asiko ọdun kekere ati ọdun nla ni awọn eegun kan maa n jade paapaa ni awọn ipinlẹ ila oorun Naijiria ni eyi to de maa n fa igbokegbodo ọkọ.

Ogbeni Kehinde Adeleye to jẹ adari ajọ ẹṣọ oju popo ni ẹkun Benini to jẹ RS5 lo ṣo eyi ni asiko ipolongo alaafia loju opopona ni ilu Onitsha, ipinlẹ Anambra lọjọbọ.

Adeleyẹ ni latẹyinwa ni wọn ti woye pe ọpọ igba ni jijade awọn ara ọrun ati bi wọn ṣe n jo loju titi maa n di igbokegbodo ọkọ lọwọ.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ara orun n fayo han ti opo si n telee

O ni lọtẹ yii, ọwọ ofin maa mu eegun ti ko ba rin bo ṣe yẹ ko rin daadaa.

Adeleye ṣalaye siwaju pe aṣẹ yii wa lati oke lọdọ Ogbeni Boboye Oyeyemi to jẹ ọga agba pata fun ajọ naa.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Awon ara orun maa n sadura fawon ara aye fun odun tuntun

Ẹni to paṣẹ pe ki gbogbo ara ọrun tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.

Ajọ FRSC ni opọ igba si ni awọn ijamba ọkọ to ba ṣẹlẹ yii maa n mu ẹmi dani.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra

Bakan naa ni Adeleye fi imoore ajọ naa han si ijọba Anmbra fun atilẹyin wọn lati rii pe ẹmi ati dukia awọn eniyan loju popo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Ni afikun, Adeleyẹ kilọ fawọn awakọ ati ọlọkada lati ṣora ṣe loju popo nitori pe ẹmi ko ni aarọ rara.

Adari ajọ ẹṣo oju popo fun ipinlẹ Anambra, Ogbeni Andrew Kumapayi ni ajọ FRSC ti ṣetan lati pese aabo to peye fun ẹmi ati dukia awọn eniyan lasiko ọdun kekere ati ọdun nla to m bọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBalogun market fire: Olubadamọran gomina sọrọ lori ina náà

Kumapayi ni awọn ajọ ẹṣo oju popo ti sami si awọn agbegbe to maa n saaba ni ipalara dani ni eyi ti wọn ti pin awọn akọṣẹmọṣẹ oṣiṣẹ lọ sibẹ lati rii pe ko si wahala lasiko ọdun keresimesi yii.

Bakan naa lo ni ki awọn eeyan fi aayọ du[pẹ oore ki wọn sa fun iwa pipa ara ẹni lasiko ọdun nitori ironu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Related Topics