Yemi Osinbajo: Ẹgbẹ́ àwọn àgbààgbà Yorùbá ní Osinbajo kò gbọdọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀

Yemi Osinbajo Image copyright Twitter/Yemi Osinbajo
Àkọlé àwòrán Yemi Osinbajo: Ẹgbẹ́ àwọn àgbààgbà Yorùbá ní Osinbajo kò gbọdọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀

Ọrọ n ba moko moro bọ lori aawọ to n ṣẹlẹ laarin igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo atawọn kan nile iṣẹ aarẹ Naijiria.

Ẹgbẹ agbaagba nilẹ Yoruba, YCE lo rọ igbakekeji aarẹ wi pe ko ma kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ YCE rọ Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko ma ṣe gbọ ohun tawọn kan n sọ fun un lori ọrọ Osinbajo wi pe ko ranti bi Osinbajo ṣe duro ti i lati igba ti wọn ti jọ bẹrẹ.

Lọjọ Ẹti ni ileeṣẹ aarẹ fidi rẹ mulẹ pe Aarẹ Muhammadu Buhari lo paṣẹ idaduro lẹnu iṣẹ fawọn oluranlọwọ marundinlogoji igbakeji aarẹ Osinbajo.

Amọ ileeṣẹ aarẹ ṣalaye pe dida ti wọn da awọn oluranlọwọ Osinbajo duro nii ṣe pẹlu igbiyanju ijọba apapọ lati din owo ti ijọba n na fun iṣejọba ku.

Garba ṣalaye loju opo twitter rẹ pe:

Atejade naa ni ọrọ idaduro yii naa ti kọkọ kan diẹ ninu awọn oluranlọwọ Aarẹ.

Garba Shehu ni awọn ipo oloṣelu kan lawọn ti yọ kuro ti wọn ko si tun awọn eeyan miran yan si ipo mii bi buhari ṣe wọle lẹẹkeji.

O ni ko si ija laarin Buhari ati Osinabjo lasiko yii.

Ṣe Laolu Akande n parọ ni?

Ṣaaju ni Ogbeni Laolu akande to jẹ oluranlọwọ fun igbakeji aarẹ Oṣinbajo ti kọkọ fi sita pe irọ to jina si ootọ ni pe Aarẹ Buhari da awọn oluranlọwọ Oṣinbajo marundinlogoji duro lẹnu iṣẹ wọn

Ṣugbọn akọwe agba ajọ ẹgbẹ agbaagba Yoruba, Ọmọwe Kunle Olajide sọ pe awọn ti wọn n gbogun ti Osinbajo n ṣe bẹẹ nitori ibo aarẹ ọdun 2023 ni.

Ọmọwe Olajide fikun ọrọ rẹ pe ko si idi kankan to le mu ki Osinbajo kọwe fipo silẹ niwọn igba to jẹ pe awọn ọmọ Naijiria jọ dibo yan oun ati aarẹ Buhari papọ ni.

Image copyright Twitter/Prof Yemi Osinbajo
Àkọlé àwòrán Yemi Osinbajo: Ẹgbẹ́ àwọn àgbààgbà Yorùbá ní Osinbajo kò gbọdọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀

O rọ igbakeji aarẹ pe ko tẹsiwaju lati maa ba aarẹ Buhari ṣiṣẹ pọ pẹlu inu kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ