US election 2020: Ibú-owó Bloomberg fẹ́ wàákò pẹ̀lú Trump nínú ìbò ààrẹ Amẹrika

Michael Bloomberg Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán US election 2020: Ibú-owó Bloomberg fẹ́ wàákò pẹ̀lú Trump nínú ìbò ààrẹ Amẹrika

Ọlọrọ Michael Bloomberg to ti figba kan jẹ Méyọ̀ to dari ilu New York ti fi erongba rẹ han lati dije dupọ aarẹ ilẹ Amẹrika ninu ibo aarẹ ọdun 2020.

Ọgbẹni Bloomberg ti kọwọ bọwe lati kopa ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu Democrat ti yoo waye nipinlẹ Alabama.

Ti o ba jawe olubori ninu ibo abẹle, a jẹ wi pe oun ni yoo tan kangbọn pẹlu Aarẹ Donald Trump ti yoo dije fun saa keji labẹ asia ẹgbẹ oselu Republican.

Ọgbẹni Bloomberg gan an ko tii kede fun ra rẹ wi pe oun yoo dije fun ipo aarẹ ninu ibo gbogbogbo ọdun to n bọ.

Ṣugbọn agbẹnusọ rẹ, Jason Schechter ti sọ f'awọn akọroyin pe Bloomberg yoo kede erongba rẹ lọsẹ to n bọ.

Iroyin sọ pe Ọgbẹni Bloomberg pinnu lati dije fun ipo aarẹ lẹyin to sọ pe ko si ẹni to le ba aarẹ Trump figagbaga ninu awọn to fẹ kopa ninu ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu Democrat.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko sẹni to le koju Trump ninu awọn to tii jade

Bloomberg to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin atawọn mẹrindinlogun miiran ni wọn yoo jọ waako ninu idibo abẹle Democrat bayii.

Joe Biden to jẹ igbakeji aarẹ ilẹ Amẹrika lo si n siwaju ninu awọn to fẹ dije fun ipo aarẹ fẹgbẹ Democrat, nigba ti Sẹnẹtọ Bernie Sanders ati Elizabeth Warren si n tẹ le e.

Image copyright Getty Images

Aarẹ Trump tilẹ sọ lọjọ Ẹti pe enikan to le ba oun figagbaga ninu ẹgbẹ Democrat naa ni Ọgbẹni Bloomberg, amọ oun naa kere.

Bloomberg gbero lati dupo aarẹ gẹgẹ bi ọlọdanni ninu ibo aarẹ tọdun 2008 ati tọdun 2016.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ

Bakan naa lo sọ ninu oṣu kẹta ọdun yii pe oun ko ni dije ninu ibo aarẹ ọdun 2020.

Loṣu keje ọdun 2020 lẹgbẹ oṣelu Democrat yoo kede nibi apero wọn niluu Wisconsin ẹni to yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo aarẹ ti yoo waye loṣu kọkanla.

Ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 1942 ni wọn bi Bloomberg ni Brighton, Massachusetts, lorilẹ-ede Amẹrika.

Fasiti Johns Hopkins lo ti kọkọ kawe ko to gboye MBA ni fasiti Harvard.

O ṣe iyawo pẹlu Susan Brown-Meyer lọdun 1975, ṣugbọn wọn kọ ara wọn sile lọdun 1993.

Bloomberd to bi ọmọ meji jẹ ọkan lara awọn eeyan to lọrọ ju lagbaye nigba ti wọn ṣi ohun ini rẹ si biliọnu mẹtalelaadọta.

Bloomberg jina si aarẹ Trump ninu ọrọ nini, nitori biliọnu mẹta ni gbogbo ohun in Trump jẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat ni Bloomberg to fi di ọdun 2001, o darapọmọ ẹgbẹ Rupublican lọdun 2001.

Bloomberg da ẹgbẹ oṣelu ara rẹ ṣe laarin ọdun 2007 si 2018.

Ṣugbọn o pada si Democrat lọdun 2018 bibi to wa di akoko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'