Wo àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun mẹ́tàlá tí àjọ ọ̀hún fọ́nka síta

Image copyright @Nigeria Police
Àkọlé àwòrán Eyi waye lasiko ti wọn n wọ okun fun aṣẹṣẹ yan igbakeji ọga ọlọpaa ni olu ile iṣẹ ọlọpaa ni Aabuja

Oga ọlọpaa, Muhammed Adamu ti paṣẹ atunto si ẹkun igbakeji ọga ọlọpaa mẹtala ni Naijiria.

Frank Mba to jẹ agbẹnusọ awọn agbofinro lo fi atẹjade naa sita lọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla ọdun yii ni eyi ti wọn ti ṣẹṣẹ sọ awọn kọmiṣọnna ọlọpaa kan di igbakeji ọga agba ọlọpaa Naijiria.

Frank Mba ni ọtọọtọ ni iṣẹ akanṣẹ ti ọkọọkan awọn agbofinro ti wọn ṣẹṣẹ gba igbega wọnyii a maa mojuto ninu ẹka iṣẹ ọlọpaa Naijiria.

Wo orukọ ati ipo awọn agbofinro ti agbega tuntun naa de ba:

1) AIG Dan Bature,fdc - AIG DFA FHQ

2) AIG Hyelasinda Kimo Musa - AIG PMF

3) AIG Yunana Y. Babas, mni- AIG Zone 8 Lokoja

4) AIG Dan Mallam Mohammed,fdc - AIG SPU

5) AIG Mua'zu Zubairu Halilu - AIG CTU

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ

6) AIG Rabiu Yusuf - AIG ICT

7) AIG Ahmed Iliyasu - AIG Zone 2, Lagos

8) AIG Mohammed Uba Kura - AIG Maritime

9) AIG Zaki M. Ahmed - AIG Zone 6, Calabar

10) AIG Zama Bala Senchi - AIG ọlọpaa awọn agbegbe kọọkan (Community Policing)

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra

11) AIG Bello A. Sadiq - AIG Zone 1, Kano

12) AIG Austin Agbonlahor Iwero,fdc - AIG DOPS FHQ

13) AIG Lawal Ado - AIG Works

Oga agba pata fawọn agbofinro gba awọn aṣẹṣẹyan sipo wọnyii nimọran lati lo iriri ati ọgbọn wọn daadaa fun ipese aabo fun ẹmi ati dukia awọn eniyan Naijiria.

Lọgan ni awọn igbakeji ọga agba tuntun wọnyii a bẹrẹ iṣẹ nibi ti wọn gbe wọn lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'