NEPA: Kò ní sí iná mọ̀nàmọ́ná ní Eko láwọn èèyàn n sọ̀rọ̀ lé lọrí

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ọpọ ero gba pe ko tọ si awọn EKEDC lati sọrọ lori ina bayii

Ileeṣẹ EKEDC àti IKEDC to n pese ina mọnamọna nipinlẹ Eko ti dẹbu ina to n ṣe segesege ru awọn irinṣẹ to n pin ina ọba.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lori ayelujara lo ti n sọrọ lori ina ọba to dorikodo nipinlẹ Eko.

Wọn n sọrọ naa nipa lilo #NEPA, #Blackout, #Nationwide lati alẹ ana, ọjọ Ẹti lataari ina ọba to di nkan mii.

Ileeṣẹ Eko Electricity Distribution Company (EKEDC) to maa n pin ina ati odiwọn iye owo ti awọn ọmọ Naijiria to n lo ina maa san nipinlẹ Eko ni aisi ina ọba kii ṣe ẹbi awọn.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Kete ti wọn sọrọ lori twitter lawọn eeyan ti n da wọn lohun

EKEDC ati Ikeja Electric Distribution Company sọrọ loju opo twitter wọn pe irin iṣẹ lo dẹnu kọle to ṣokunfa aisi ina yii.

Lẹyin eyi ni wọn tun bẹ awọn eniyan ki wọn ni suuru ni eyi ti wọn fi ni iṣẹ ti n lọ lori ṣiṣe atunṣe to yẹ si awọn irin iṣẹ wọnyii to dẹnu kọlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIllegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ

Kete ti wọn fi eyi lede tan ni awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni fun wọn lesi pada. awọn kan ni ki PHCN naa ni suuru lori pinpin bíìlì iye owo ti àwọn maa san.

Bẹẹ naa ni awọn eniyan miran n gboriyin fun ileeṣẹ mọnamọna pe ikede naa dara ti wọn fi sita

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aadota odun ree ti e ti n paro atunse ise yin fawon omo Naijiria lero awon kan

Awọn mii bi hunter bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu PHCN pe o ti le laadọta ọdun tawọn eeyan ti n ni suuru fun wọn ti wọn ko si yipada di asiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsteogenesis, aisan níní egungun tó rọ̀ ló ń ba Efia fínra

Awọn miran n parọwa fun PHCN ki wọn tete pari iṣẹ to yẹ nitori ooru ti n mu diẹ lasiko yii