Yoruba Films: Toyin Abraham ní 'gbogbo èèyàn loníbárà', Ijebu ta sí Odunlade

Pasuma, Sanyeri, Toyin Abraham ati Odunlade Adekola Image copyright Other

Ninu iroyin ohun to ṣẹlẹ lagbo awọn gbajugbaja oṣere Yollywood lọsẹ to kọja, Toyin Abraham lo sọrọ to ya ọpọ lẹnu nigba to sọ pe gbogbo eeyan ni onibara laye.

Toyin Abraham

Toyin ṣalaye pe awọn eeyan kan wa ti wọn n tọrọ owo, o ni iru isọri awọn onibara kan niyii.

Toyin tun sọ pe awọn kan tilẹ wa to jẹ wi pe owo ko jẹ awọn niya, amọ idunnu ni wọn n wa eyi lo si jẹ ki wọn jẹ onibara.

Toyin Abraham tun ṣalaye siwaju sii pe ilera lawọn eeyan kan n tọrọ ni tiwọn lọwọ Ọlọrun bo tilẹ jẹ pe owo ko jẹ wọn niya.

Odunlade Adekola

Oṣere Odunlade Adekola ni tirẹ fi dawọn ololufẹ Yollywood loju ni pe awọn yoo maa tẹsiwaju lati maa mu inu wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn kọlọnbiti ẹda kan si n ji iṣẹ wọn ta.

Odunlade ni sọ nipa fiimu ''Ajẹbi'dan eleyi to ṣe fun ra rẹ.

Odunlade ni kawọn eeyan foju sọna fun fiimu naa wi pe yoo jade ni ko pẹ.

Sanyẹri

Nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọkan ninu olori Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ni Afonja Mukaila Olaniyi ti ọpọ mọ si Sanyeri ti ṣe opin ọsẹ yii.

Koda oun ati ilumọọka olorin Fuji, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma jọ pade nibi ayẹyẹ ọhun to waye niluu Oyo.

Sanyẹri tilẹ rọ awọn eeyan loju opo Instagram rẹ lati mura ṣiṣẹ wọn, bakan naa lo gbadura fun ibukun Eleduwa fun wọn.

Muyiwa Ademola

Muyiwa Ademola naa sọrọ lori awọn fiimu to ti jade lati ọwọ awọn gbajugbaja oṣere Yollywood.

Image copyright Other

Ọ kọkọ sọ nipa fiimu ti akọle rẹ jẹ ''Survival of Jelili'' eleyi to pe ni fiimu to le dẹrin pa oṣonu.

Bakan naa lo sọrọ nipa fiimu Ajẹbi'dan eleyi to jẹ iṣẹ ọwọ Adekola Odunlade.

Ibrahim Chatta

Gbajugbaja oṣere Ibrahim Chatta naa sọ nipa fiimu ti akọle rẹ jẹ ''Survival of Jelili'' eyi to jẹ iṣẹ ọwọ Femi Adebayo

Oun naa jẹri sii pe ẹrin arin takiti wa ninu ere ọhun eyi ti yoo jade lọjọ kẹfa oṣu kejila.

Ijebu

Gbajugbaja osere tiata, Ọlatayọ Amokade ti gbogbo eeyan mọ si Ijẹbu, ṣalaye iha ti idile rẹ kọ si isẹ to n se.

Ijẹbu, lasiko to n kopa lori eto ifọrọwanilẹnuwo lori BBC Yoruba salaye pe, inu iyawo oun kii dun si eebu ti akẹẹgbẹ oun, Ọdunlade Adekọla maa n bu oun lasiko ti awọn ba n sere tiata.

Image copyright Ijebu

Ijẹbu ni bi o tilẹ jẹ pe eebu naa ko ni itumọ kankan si oun nitori ere lasan ni, amọ iyawo oun ko fi bẹẹ nifẹ si iru iwa bayii.