#VerifiedTacha: Àwọn mánigbàgbé tí Olùdásílẹ̀ Twitter Jack Dorsey ṣé làsìkò ìrìnàjò rẹ sí Áfríkà

Aworan oludasilẹ Twitter lasiko abẹwo rẹ si Naijiria Image copyright twitter.com/jack

Ọjọ keje oṣu Kọkanla ni Jack Dorsey, oludasilẹ ileeṣẹ Twitter balẹ biba s'orileede Naijiria ni itẹsiwaju irinajo rẹ si awọn orileede kan ni Afrika.

Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ saaju, o ni ohun yoo ṣepade pẹlu awọn oniṣowo imọ ẹrọ ọlọdani kaakiri ilẹ Afrika loṣu Kọkanla ọdun 2019.

Lasiko to wa ni Naijiria, o ba awọn eeyan orisirisi ṣe ipade koda awọn miran tun ri ore ọfẹ anfaani lati ba a sọrọ nipa mimu idagbasoke ba iṣẹ wọn.

Ile ẹkọ fasiti ilu Eko wa lara awọn ibi to kan si ti o si jomitoro ọrọ pẹlu awọn alaṣẹ ati akẹkọ nibẹ.

Yatọ si Unilag, o tun ṣe ipade pẹlu awọn onikarakata owo ori ayelujara Bit Coin.

Image copyright twitter.com/jack

Bi o ti ṣe n kaakiri, bẹẹ ni o n fi aworan awọn ipade rẹ han loju opo Twitter

Awọn ti Mercy BB Naija naa rawọ ẹbẹ si Jack Dorsey

Lasiko abẹwo rẹ, oju opo rẹ kun fun orisirisi ibeere ṣugbọn ọkan to jọ bi irawọ ẹbẹ si ni eyi tawọn ololufẹ Mercy, olukopa BBNaija kọ si i pe ki o tẹle Mercy lori Twitter.

Ṣaaju ni Jack ti tẹle Tacha lori Twitter tawọn ololufẹ Tacha si n dupẹ lọwọ rẹ pe o tẹle e.

Nigba ti ilẹ ọjọ Iṣẹgun yoo fi mọ, ariwo pe Jack Dorsey fi ontẹ jan Tacha ti bi #VerifiedTacha loju opo Twitter ti awọn ti Tacha si n ki ara wọn ku orire.

Eyi to jẹ babanbari lasiko irinajo rẹ si Naijiria ni igba to gbiyanju lati jo Soapy.

Arakunrin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Real_jaeflex lo fi fidio naa soju opo Twitter ti a si ri Jack Dorsey ati Minisita feto ọrọ Aje ni Naijiria tẹlẹ ri Ngozi Okonjo Iweala ti wọn n fi ẹsẹ ra ijo pẹlu orin Naira Marley.

Irinajo rẹ tẹsiwaju si orileede Ghana lẹyin to dagbere o digba kan na fun Naijiria.