Wo Bullet, ọmọ ọdun mẹjọ tó fẹ́ lùwẹ̀ wọ Olympics
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olympics ni ọkàn mi wà gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ - Aidan Dumuje

Ọlọrun lo mọ ọdun gan ti Aidan Dumuje Abulu bẹrẹ si ni luwẹ to fi jẹ wi pe ni ọmọ ọdun mẹjọ afi bii ẹja ni wiwẹ rẹ.

Ṣugbọn pẹlu iwadii BBC, ọjọ́ mẹ́fà ni ọmọ ọdún mẹ́jọ olùwẹ̀ yìí fi maa ń gbaradì lọ́sẹ̀.

Ipo to to gbedeke maaki ida ọgọrun ni akọnimọọwẹ rẹ, Joe Jacobs fun Aidan gẹgẹ bi ọmọde omuwẹ.

"O da yatọ ninu gbogbo awọn ọmọde ti mo n kọ, oun lo yara ju, oun ti mo n kọ wọn tete maa n ye e".

Ni ti Aidan, ifẹ ọkan rẹ ni lati gba ipo awọn ọba omuwẹ lagbaye bii Michael Phelps ko si gba ami ẹyẹ idije agbaye Olympics.

O ni "bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ odò wíwẹ̀ lọ́jọ́ 'wájú, mo fẹ́ kí ẹ máà rántí mi".