Makinde vs Adelabu: Ogunlọ́gọ̀ èrò ṣàbẹ̀wò àtìlẹyìn sí Seyi Makinde

Makinde ati awọ̀n ọmọ igbimọ alasẹ rẹ n ba ọgọọrọ ero sọrọ Image copyright @seyiamakinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Sey Makinde gbalejo obitibiti ero nileesẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ loni, lati wa se abẹwo awa lẹyin rẹ si.

Abẹwo naa lawọn eeyan yii se pẹlu oniruuru lati safihan ifẹ ti wọn ni si gomina Seyi Makinde pe gba gba gba lawọn wa lẹyin rẹ lẹyin idajọ tileẹjọ kotẹmilọrun da lọjọ Aje.

Nigba to n gbalejo awọn ọgọọrọ eeyan naa, Gomina Seyi makinde ni se ni ẹgbẹ oselu APC dabi afomọ ti ko ni gbongbo, to si n wa gbongbo ti yoo dirọ mọ pẹlu asẹ ile ẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe ohun to n waye ni ipinlẹ Ọyọ ko lee dabi awọn isẹlẹ to ti waye sẹyin nipinlẹ Ọsun ati Ekiti nibi ti idajọ ile ẹjọ ti le ijọba to wa lori aleefa kuro.

Image copyright @seyiamakinde

Makinde ni abajade esi ibo gomina to waye lọjọ kẹsan osu kẹta ọdun 2019 fihan pe ẹgbẹ oselu PDP jẹ itẹwọgba araalu jakejado ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ti kẹyin si ẹgbẹ oselu APC.

O wa fọwọ gbaya pe mimi kankan ko mi oun lori idajọ naa, ti oun si n ba isẹ oun lọ gẹgẹ bii gomina, to si rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lati bomi suuru mu.

Image copyright @seyiamakinde

"Se ibi yii jọ Ọsun abi Ekiti, wọn fẹ ba aseyẹ wa jẹ. Ko si ohunkohun to sẹlẹ si asẹ tẹ gbe le mi lọwọ lati maa dari yin, ti wọn ba sọ pe awọn jawe olubori nile ẹjọ, ki lo de ti wọn ko se wa gba akoso ile ijọba laarọ oni?'

"Ibi gbogbo yika ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti kọ wọn. Wọn kọ wọn ni Ibadan, Ọyọ, Ibarapa, Oke Ogun ati Ogbomosọ, ki lo tun wa ku ti wọn fẹ se."

Image copyright @seyiamakinde

Makinde ni kawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ mase mikan rara, tori ẹgbẹ APC kan n wa ọna ti ko fi ni parun ni.

Ìdájọ́ ilé ejọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti já ìràwọ̀ Makinde gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Oyo - Jiti Ogunye

Image copyright Facebook/Seyi Makinde

Ọrọ n ba moko moro bọ lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to waye lọjọ Aje lori awuyewuye ibo gomina ipinlẹ Oyo.

Iyalẹnu ni idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ọjọ Aje fun ọpọ eeyan lẹyin tawọn adajọ sọ pe Gomina Seyi Makinde jawe olubori ninu idibo lọna to tọ ṣugbọn ile ẹjọ wọgile idajọ igbimọ to n ri si awuyewuye idibo gomina nipinlẹ naa.

Gbajugbaja agbẹjọro, Jiti Ogunye to ba BBC Yoruba woye pe idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ku diẹ kaato, ati pe o so ọlọgbọn kọ.

Ogunye ni ''idajọ aabọ ni igbimọ igbẹjọ ile ẹjọ kotẹmilọrun da nitori wọn ti ja irawọ Gomina Makinde lẹyin ti wọn wọgile idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun akọkọ ti wọn si tun sọ pe ki Makinde ṣi maa tẹsiwaju ni ọfiisi rẹ.''

Agbẹjọro Ogunye ṣalaye siwaju sii pe Makinde to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ati Adebayo Adelabu to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu APC to pe e lẹjọ lo le lọ si ile ẹjọ to ga julọ bayii.

Ọgbẹni Ogunye lati igba ti ọun ti bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro, oun ko ri iru idajọ bayii ri, amọ o sọ pe oun yoo ṣe ayẹwo idajọ naa finifini lati mọ ni pato ohun to mu awọn adajọ da iru ẹjọ bẹẹ.

Agbẹjọro Ogunye sọ pe idajọ ara o rọkun ara o rọ adiyẹ ni idajọ yii maa ja si ti ọkan ninu Makinde tabi Adelabu ko ba gbe idajọ yii lọ si ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Ẹwẹ, Gomina Makinde ti sọrọ pe mimi kan ko le mi oun lẹyin ti ileẹjọ ti sọ pe k'oun tẹsiwaju iṣẹ oun gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo.