Ejò tí a gé lórí tó ń jẹ aporó ní APC - Seyi Makinde
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Makinde vs Adelabu: Makinde ní ìjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC lé dànù

Ẹsẹ ko gba ero nile ijọba to wa nilu Ibadan loni nigba ti ọpọ ero wa se abẹwo awa lẹyin rẹ si gomina Seyi Makinde lati safihan ifẹ ti wọn ni si.

Nigba to n gbalejo awọn ọgọọrọ eeyan naa, Gomina Seyi Makinde ni se ni ẹgbẹ oselu APC dabi afomọ ti ko ni gbongbo, to si n wa gbongbo ti yoo dirọ mọ pẹlu asẹ ile ẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe ohun to n waye ni ipinlẹ Ọyọ ko lee dabi awọn isẹlẹ to ti waye sẹyin nipinlẹ Ọsun ati Ekiti nibi ti idajọ ile ẹjọ ti le ijọba to wa lori aleefa kuro.