Ìyàwó mi fẹ́ràn ìrìnàjò òfurufú ni mo ṣe kọ́ ilé Bàálù yìí fún un
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n

Said Jamal jẹ oniṣẹ ile kikọ. O ni oun ti bẹrẹ ile to n kọ fun iyawo rẹ yii lati ọdun 1999. Yara kan lo kọkọ pari ti oun ati ẹbi rẹ si ko sinu ẹ titi ti wọn fi kọ ọ de ibi ti o de bayii. Koda ko ṣi tii pari.

Ni agbegbe Asokoro ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja ni ile awoyanu nla yii kalẹ si.

"Nigba ti mo fẹ iyawo mi, awọn obi rẹ sọ fun mi pe o fẹran lati maa rinrinajo". Eyi lohun ti Said sọ fun akọroyin BBC.

Liza Jammal ni iyawo Said. Ṣe loju maa n ti i ti ko si fẹran lati maa foju han tori naa, ọmọ rẹ ọkunrin to gbẹnu rẹ sọrọ Mohammed Jammal ti o gbajugbaja pẹlu orukọ rẹ, "White Nigerian" sọ bi wọn ṣe bẹrẹ ile naa.

O ni "lati ọmọ ọdun mejila ni mo ti gbanju ba baba mi to n kọ ile ọkọ baalu yii titi ti mo fi dagba bayii".

"Itan mi kii ṣe itan ifẹ nikan. bi ko ṣe kiko ipa". Eyi ni Said sọ.