Ibadan Refuse: Kọmísánà fọ́rọ̀ àyíká ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní bó ṣe jẹ́, kò ṣàdédé wáyé

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIbadan: awon araalu figbe bonu pe ilu doti

Oriṣiriṣi awọn panti ati ilẹ ti awọn eeyan n da si aarin igboro, ti sọ awọn adugbo kan ni ilu ibadan ti o jẹ olu ilu ipinlẹ Ọyọ ti aatan.

Ikọ BBC Yoruba rin kaakiri awọn adugbo bii Ring Road, Mọkọla, Eleyẹle, Iwo Road, Mọnatan ati Iyana Church lati mọ bi imọtoto aarin ilu Ibadan se ri.

Amọ iriri wa fi idi ọrọ mulẹ pe, pupọ ninu awọn adugbo yii ni ko dun un wo nipasẹ awọn panti ti o kun gbogbo opopona kaakiri eyi ti ko wu oju ri rara.Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn araalu to ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ ṣalaye wi pe, obitibiti idọti to gba igboro ilu Ibadan kan lee ṣe akoba fun ilera awọn ara ilu.

Wọn wa parọwa si ijọba lati pesẹ agba nla ti awọn eeyan le ko ilẹ ati idọti si, bakan naa si ni wọn lo pọn dandan fun ajọ kolẹkodọti ni ipinlẹ Ọyọ lati ṣe iṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ.

Lasiko to n fesi si ọrọ naa, kọmisana fun ọrọ ayika ni ipinlẹ Ọyọ, Asofin Kehinde Ayọọla ṣalaye wi pe lootọ ni igboro ilu Ibadan dọti ṣugbọn ọrọ ko dede ri bẹẹ, o ni bo se jẹ.

Ayọọla sọọ di mimọ pe lọjọ melo kan sẹyin ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde gba iṣẹ lọwọ ileeṣẹ aladani to n ṣiṣẹ kolẹkodọti tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, ti o si yan adari tuntun fun ileeṣẹ to mojuto imọtoto ilu.

Kọmisana naa fi kun pe, laipẹ laijinna ohun gbogbo yoo yipada lorii imọtoto ilu Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ, lọgan ti adari tuntun lẹka ileeṣẹ to n ṣe imọtoto ilu, ba wọle s'ẹnu iṣẹ.