Europe Returnee: Fatmata ní oṣù mẹ́fà ni wọn fi bá òun ṣùn ní aṣálẹ̀ Sahara

Obinrin kan n rin lọ leti okun

Ọpọ awọn ọdulawọ to kuna lati de ilẹ Europe lo pada si orilẹede abinibi wọn, sugbọn ipadabọ to mu ikoro dani lo maa n jẹ fun wọn.

Lorilẹede Sierra Leone, se lawọn mọlẹbi ati ọrẹ awọn eeyan to sẹsẹ pada de lati oke okun maa n kẹyin si wọn, ti wọn si maa n ri wọn bii ẹni ijakulẹ, paapaa nigba to jẹ pe ọpọ awọn to rinrin ajo naa lo saba maa n gbe owo awọn obi wọn, ki wọn to sa lọ soke okun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti obinrin kan to sẹsẹ de n sọ ohun ti oju rẹ ri fun BBC, eeyan yoo fẹ le ba a sunkun nitori a ti ju wọn lo ba lọ, amọ nigba ti yoo dari de, ko jẹ nkankan mọ.

Ẹ jẹ ka gbọ alaye iriri ohun ti oju obinrin kan to rinrin ajo lọ soke okun naa ri ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu BBC.

Fatmata: $2,600 owo ẹgbọn mi ni mo gbe lati rinrinajo soke okun amọ osu mẹfa ni wọn fi ba mi lo pọ ni asalẹ Sahara

Fatmata, ẹni ọdun mejidinlọgbọn to wa latilu Freetown lorilẹede Sierra Leone bu sẹkun nigba to ranti osu mẹfa to lo loju ọna silu oyinbo, to si gba asalẹ Sahara kọja.

$2,600 owo ẹgbọn rẹ obinrin to ni ki Fatmata fi bẹrẹ okoowo asọ tita, lo ji gbe fi gba ilu oyinbo lọ pẹlu ireti pe ibẹ yoo dara.

Fatmata ni oun ni lero pe ti oun ba de ilu oyinbo, oun yoo fi ilọpo mẹta owo ti oun ji gbe ransẹ pada si anti oun, ti oun yoo si maa tọju iya ati anti oun.

Sugbọn owo ti Fatmata ji gbe yi ti pa okoowo anti rẹ lara pupọ ju, to si ti da aawọ silẹ laarin oun ati iya wọn, nitori anti rẹ gba pe iya awọn wa lẹyin Fatmata to lo fi gbe owo oun.

Fatmata sọrọ pẹlu omije loju pe, ọkunrin ẹya Tuareg kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ahmed, to jẹ darandaran, lo mu ohun lẹru ni asalẹ Sahara.

O ni "ọkunrin naa dabi omiran, to si dudu kirikiri lawọ, ilo ẹru si lo maa n lo mi, ti yoo si tun sọ fun awọn ọrẹ rẹ lati wa ba mi ni ajọsepọ ninu ile rẹ, ojoojumọ ni wọn n fi iya nla jẹ mi."

Sugbọn kaka ko san lara iya ajẹ lọrọ Fatmata nitori bo se bọ lọwọ Ahmed lo tun ko sọwọ awọn akonisowoẹru ko lọ fi pamọ si aja ilẹ lorilẹede Algeria.

Idi niyi ti Fatmata se pinnu lati pada sile nigba ti iwaju ko se lọ, ẹyin yoo sa se pada si, to si bẹbẹ fun owo ọkọ lati pada sile sugbọn se ni wọn foju tẹmbẹlu rẹ pe bo se lọ lo se bọ.

Ni kete ti aburo rẹ ọkunrin gbọ pe Fatmata de si ilu Freetown lati oke okun to lọ lọwọ ofo, lo pe lori aago pe ko ba dara ko gbe si ajo ju bo se pada wa sile lọ.

"Ko ba san fun ọ ko ti ku sibi to lọ ju bo se pada wa sile lọ. O ko mu ohunkohun bọ, to si san ọwọ pada wa sile lọwọ ofo, yoo dara ko ma yọju sile rara."

Koda, iya rẹ ko tiẹ sopo lati wa ki pe o kaabọ lati irinajo, ti oun gan ko si igboya lati lọ ki iya rẹ nile, ko si ri aaye wo ọmọ ọdun mẹjọ to fi silẹ lọ silu oyinbo.