Falomo Robbery: ọkunrin kan tó jáde nílé ìfowópamọ́ làwọn adigunjalè tọpasẹ̀ rẹ̀

Ikorita Falomo Image copyright Others

Osisẹ ọlọpa kan ti jade laye, ti ọlọpa obinrin kan ati ẹ́nikan miran si fara gba ọ̀ta ibọ̀n lori afara Onikan, ladugbo Falọmọ, nilu Eko.

Nigba to n fidi isẹ́lẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, osisẹ alarena fun ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Eko, Elkana Bala salaye pe, deede aago mejila ọsan ni isẹlẹ naa waye.

O ni ohun to sokunfa iku ojiji yii ni bi awọn adigunjale se tọpasẹ ọkunrin kan to sẹsẹ gba owo nile ifowopamọ kan to wa ni adugbo Falomo de ori afara onikan, ti wọ̀n si sẹburu rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Elkana salaye pe awọn alọkolohunkigbe ọhun gba baagi ti ọkunrin naa gbe lọwọ, ti wọn si ro pe owo to lọ gba nile ifowopamọ ọhun lo wa ninu rẹ laimọ pe obinrin naa ti fi owo ọhun pamọ si ara rẹ.

O fikun pe bakan naa ni wọn tun gba ẹrọ ibanisọrọ ọkunrin naa ati ẹrọ kọmputa alagbeletan rẹ, ti wọn si fẹsẹ fẹ.

Osisẹ alarena ọlọpa Eko fikun pe, osisẹ ọlọpa to wa nisalẹ afara Onikan naa ba yinbọn mọ awọn adigunjale ọhun, amọ ibọn naa ko ba awọn adigunjale ọhun.

O ni awọn adigunjale yii naa da ibọn pada fun ọlọpa yii, to si baa laya, eyi to mu ko dagbere fun aye loju ẹsẹ, ti ọta ibọn miran si tun ba obinrin ọlọpa kan, ati eeyan kan mii, ti wn n gba itọju lọwọ nile iwosan.