Lagos Fire: Lasema ní iná ba tó gbiná nínú yàrá kan ló fa sábàbí

Ile to jona ni Tejuoso Image copyright LASEMA

Kaka ki ewe agbọn dẹ ni ọrọ ijamba ina to n waye nilu Eko lẹnu lọọlọ yii, nitori ko ko ko lo n le si.

Idi ni pe akọtun ina miran tun ti sẹyọ lọsan oni ninu ile kan to wa ladugbo Tẹjuoso nilu Eko.

Gẹgẹ bi oludari agba fun ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, Femi Oke Osanyintolu ti salaye fun BBC Yoruba, inu ile alaja kan ni isẹlẹ ina ọhun ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọga agba LASEMA ni ina ba to sadede gbina ninu yara kan to wa ninu ile naalo sokunfa isẹlẹ yii, to si ran ka gbogbo ile ọhun.

Image copyright LASEMA

O ni ọwọja ina naa ti mu ki ogiri ile ọhun lanu, to si da wo lulẹ.

Amọ Osanyintolu fikun pe isẹlẹ ina naa ko mu ẹmi kankan lọ bi o tilẹ jẹ pe aimọye dukia lo baana ninu isẹlẹ yii.

Image copyright LASEMA

Lasema ni ọkunrin meji lo farapa ninu ijamba ina naa, ti wọn si ti gbe wọn lọ fun itọju nile iwosan.

Lọwọlọwọ bayii, ọga agba Lasema ni awọn osisẹ oun ati awọn panapana ti wa nilẹ lati bomi pa ina naa ko ma baa tan ran awọn ile to mule tii.