Seyi Makinde: Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba mi

Gomina Seyi Makinde Image copyright Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi makinde ti fọwọ gbaya pe oun yo sa gbogbo ipa oun lati ri daju pe awọn eeyan ipinlẹ naa ni igbẹkẹle kikun ninu ijọba oun.

Gomina Makinde fi ọwọ idaniloju ọhun sọya ninu ọrọ apilẹkọ rẹ nibi ipade itagbangba lori eto isuna ọdun 2020 to waye lẹkun idibo aarin gbungbun Ọyọ, ni gbọngan Atiba, nilu Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Makinde ni ijọba oun ti setan lati se atunto ilana isejọba, ki oun si se agbekalẹ ipilẹ to loorin fun isejọba alajumọse ti ilẹkun rẹ yoo si silẹ fawọn araalu.

Image copyright Oyo State Government

Gomina Makinde. ẹni ti olori osisẹ lọọfisi gomina, Oloye Bisi Ilaka soju fun salaye pe afojusun ipade ita gbangba naa ni lati jẹ ki smọ ipinlẹ Ọyọ kọọkan ni ẹnu ninu isejọba, ki ijọba si le ni imọ nipa ohun ti ijọba ibilẹ kọọkan n poungbẹ rẹ nigbaradi fun amusẹ eto isuna ọdun 2020.

Makinde ni afojusun ijọba oun ni lati mu seto ilana isejọba onidagbasokenti yoo gba to ogun ọdun, eyi ti yoo wa fun ijọba mi ati awọn isejsba ti yoo tẹle mi.

Image copyright Oyo State Government

"Bakan naa ni mo tun fẹ mu agbega ba okun ajọsepọ laarin ijọba ati awọn araalu nipa bibeere ero wọn lori isuna ọdun to n bọ."

"Yatọ si pe ma ri daju pe a lo awọn ohun alumọọni fawọn isẹ akanse to nitumọ si araalu, ati amusẹ awọn eto ti yoo mu ilọsiwaju ba eto ilera awọn eeyan ipinlẹ yii, maa tun tiraka lati ri daju pe araalu ni igbẹkẹle kikun ninu ijọba mi."

Image copyright Oyo State Government

Saaju ninu ọrọ ikinni kaabọ rẹ, Kọmisana feto isuna ati aato ọrọ aje nipinlẹ Ọyọ, Amofin Adeniyi Farintọ mẹnuba pe ipade ita gbangba naa se koko nitori igba akọkọ ree ti ijọba kan ati awọn araalu yoo joko papọ lati jiroro lori eto isuna kan ki wsn to gbe kalẹ.

Farintọ ni ijọba Seyi Makinde yoo tẹsiwaju lati maa ko akoyawọ lai fi igba kan bo ọkan ninu, ninu awọn ilana to ba gbekalẹ, ti yoo si maa gba ero araalu laaye.

Image copyright Oyo State Government

Nigba to n dahun si awọn ibeere araalu lasiko ijiroro naa, Makinde seleri pe oun yoo pese oju ọna to ye kooro si ẹkun idibo naa.

O ni oun yoo tun se agbekalẹ ẹka ajọ to n se atunse oju ọna nipinlẹ Ọyọ OYSTROMA si ẹkun naa pẹlu bi afikun se ba owo tijọba ipinlẹ naa n gba lati ọdọ ijọba apapọ pẹlu biliọnu marun naira.

Image copyright Oyo State Government

Lori ọrọ LAUTECH, Makinde ni wọn ti gbe igbimọ kan kalẹ lati sisẹ lori bi ipinlẹ Ọyọ yoo se gba akoso ileẹkọ fasiti Ladoke Akintola to wa nilu Ogbomọsọ patapata.