Kogi & Bayelsa Polls: Buhari ní ìdìbò gómìnà gbọdọ̀ lọ nírọwọ́ rọsẹ̀

Muhammadu Buhari Image copyright Twitter/Presidency
Àkọlé àwòrán Kogi & Bayelsa Polls: Buhari ní ìdìbò gómìnà gbọdọ̀ lọ nírọwọ́ rọsẹ̀

Ṣaaju idibo gomina nipinlẹ Kogi ati Bayelsa lọjọ Satide ọsẹ yii, Aarẹ Muhammadu Buhari ti kilọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo lati dena awọn janduku to ba fẹ ji apoti idibo gbe.

Buhari ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ oludamọran pataki lori ọrọ iroyin, Garba Shehu, sọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo pe ki wọn ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ki wọn rii pe awọn eeyan dibo gẹgẹ bi ẹtọ wọn.

Aarẹ Buhari sọ pe gbogbo ọna ni kawọn ẹṣọ eleto idibo fi dena ẹnikẹni to ba fẹ ji apoti idibo gbe.

Aarẹ ni ẹnikẹni ko gbọdọ dunkoko mọ ẹnikan tabi dena ẹnikẹni lati dibo gẹgẹ ẹtọ wọn.

Bakan naa ni aarẹ Buhari kepe awọn oludibo nipinlẹ Bayelsa ati Kogi lati ṣe jẹẹjẹ nibudo ibudo idibo, ki wọn si dibo lalaafia gẹgẹ bi ofin ti laa kalẹ.

Buhari sọ pe, ''nibi gbogbo ti eto idibo ti n waye ni oludije kan yoo ti jawe oloubori, ti omiran yoo si fidi rẹmi, ti Bayelsa ati Kogi kogi naa ko gbọdọ yatọ.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde vs Adelabu: Makinde ní ìjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC lé dànù

Aarẹ Buhari rọ awọn oludije lati gba esi idibo ti yoo waye bi o ba ṣe ri laidarogbodiyan silẹ.

Aarẹ ni oludije ti eto idibo ko ba tẹ lọrun laṣẹ lati gbe ile ẹjọ lọ dipo ki o da wahala silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n