Edgal Imohimi: Ìpínlẹ̀ Eko ló ti kọ́kọ́ se Kọmísánà ọlọ́pàá

Edgal Imohimi Image copyright Edgal Imohimi

Ọjọbọ ni iroyin gbalẹ pe isipo rọpo tun ti waye nileesẹ ọlọpa ilẹ wa, ti wọn si gbe awọn Kọmisana ọlọpa kan kuro nigba ti wọn fi awọn miran rọpo wọn.

Lara awọn Kọmisana ọlọpa ti wọn ni isipo rọpo ni Edgal Imohimi, ti isẹ tun gbe wa sipinlẹ Ogun gẹgẹ bii kọmisana ọlọpa fun ipinlẹ Ogun.

Edgal Imohimi jẹ odu ninu isẹ ọlọpaa, ti kii si se aimọ fun oloko awọn araalu nitori isẹ takuntakun to ti se gẹgẹ bi Kọmisana ọlọpa, paapa nipinlẹ Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O si yẹ ka mọ iru eeyan ti Edgal Imohimi, Kọmisana ọlọpa tuntun nipinlẹ Ogun jẹ.

Ọdun 1984 ni Edgal Imohimi kẹkọ gboye imọ ijinlẹ akọkọ ninu isẹ ọna nile ẹkọ fasiti Jos, to si tun gba oye imọ ijinlẹ keji ni fasiti Eko lọdun 2004.

Osu Keji ọdun 1986 ni Edgal Imohimi darapọ mọ ileesẹ ọlọpa ilẹ wa gẹgẹ bii ASP, to si sisẹ ni ọpọ awọn ẹka ileesẹ ọlọpaa kaakiri amọ ilu Eko lo ti lo ọpọ akoko naa lẹnu isẹ.

Image copyright Edgal Imohimi

Edgal Imohimi kẹkọ, to si ni imọ kikun ninu sise akojọpọ imọ fun isẹ ọlọpa ati isẹ ọlọpa ni aarin awujọ, oun si lo se agbekalẹ ipade apero akọkọ lori isẹ ọlọpa laarin awujọ ni Ikẹja, tii se olu ilu ipinlẹ Eko.

Edgal, ẹni to tun gba oye imọ Diploma ninu imọ nipa sayẹnsi isẹ ọlọpa, ti sisẹ gẹgẹ bii DPO fun agọ ọlọpa to wa ni Surulere, Ikeja laarin ọdun 1993 titi de 2011.

O tun di CSP ọlọpa ko to tun ni igbega si ipo ACP to wa lẹkun isọri ileesẹ ọlọpa kinni, ti wọn pe ni Area A to wa nipinlẹ Eko.

Edgal Imohimi tun gba iwe ẹri nileesẹ ologun ilẹ wa lọdun 2015, eyi to mu ki wọn yan gẹgẹ bii alakoso fun ẹka kiko iroyin afinuwa jọ ni olu ileesẹ ọlọpa to wa nilu Abuja.

Gẹgẹ bi akọsẹmọsẹ ninu sise isẹ ọlọpa lawujọ, Edgal ti kopa ninu ọpọ idanilẹkọ lorisirisi eyi ti ẹka to n ri si idagbasoke agbaye DFID ti United Kingdom se kokari rẹ nilu Eko, Awka ati ni Plateau.

Image copyright Edgal Imohimi

Edgal Imohimi, nigba to jẹ DPO ni ẹkun ileesẹ ọlọpa to wa ni Ikeja, se ifilọlẹ sise isẹ ọlọpa awujọ taa mọ si Community Policing, akọkọ iru rẹ, to si gbalejo ọps eeyan to ni nkan se pẹlu ọlọpa nibi to ti sedanilẹkọ fun wọn nipa bi wọn se lee ran awọn ọlọpa lọwọ lawujọ.

Edgal Imohimi, gẹgẹ bii Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Eko tun sisẹ takuntakun, lati sawari awọn akẹkọ girama mẹfa ti wọn ji gbe.

Ọjọ Kẹẹdọgbọn osu Karun ọdun 2017 nisẹlẹ naa waye ni ilegbe awọn akẹkọ girama Lagos Model College to wa ni Igbo Nla nilu Epe, ti wọn si gba idande lẹyin ọjọ marundinlaadọrin.

Edgal Imohimi ti wọ isẹ bayii gẹgẹ bii Kọmisana ọlọpa tuntun nipinlẹ Ogun.