'Olùkọ̀ kan tilẹ̀ sọ fún un pé "ẹlẹ́sẹ̀ kan ni ẹ́, oò ní 'le wẹ̀'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Crystal Chiagbu: Wọ́n sọ fún wa nígbà tó pé ọjọ́ mẹ́fà pé a máa gé ẹsẹ̀ rẹ̀

Ọrọ Beulah kọja a n sọ ireti nu, tori ko tilẹ fi aaye silẹ lati maa ronu pe o ni ipenija ara kankan lati kekere.

Lati ọmọ ọwọ ni iya rẹ ti pa ọkan pọ pẹlu idunu pe yala ọmọ lẹsẹ tabi ko ni, ko ni jẹ idiwo kankan fun igbe aye rẹ.

Eyi tun mu ki Crystal Chiagbu bẹrẹ si ni ba awọn ọmọ ti wọn bi lai lẹsẹ tabi ti ẹsẹ ati apa wọn ba ti ge ṣiṣẹ lati maye rọrun fun wọn ati lati kọ wọn pe idunu la fi n gbe 'le aye.

Oun naa ni ọmọ to ni ipenija ẹsẹ lati igba ibi rẹ ti wọn si ti sọ fun un pe wọn gbudọ ge ẹsẹ naa.

"Ni gbogbo igba ti mo ba wo o to n rẹrin, to si n mu ọmọ mii rẹrin maa n fun mi layọ".