FUTA Bullies: Ìgbìmọ̀ aláṣẹ fásitì FUTA pàṣẹ lọ rọọ́kún nílé fakẹ́ẹ̀kọ́ méje tó lù akẹgbẹ́ wọ́n

Aworan fasiti FUTA Image copyright Google

Igbimọ alaṣẹ fasiti imọ ẹrọ ilu Akure, FUTA ti paṣẹ lọ fidimọle fawọn akẹkọọ meje ni fasiti naa ti wọn da sẹria iya f'akẹgbẹ wọn kan to jẹ obinrin.

Ninu atẹjade kan ti Adegbenro Adebanjo to jẹ igbakeji adari eto ibaraẹnisọrọ fasiti naa fi sọwọ sita, wọn ni iwa bẹẹ lodi si ofin ati ilana ile ẹkọ awọn.

Lọjọ Abamẹta ni fidio kan to ṣe afihan awọn akẹkọọ kan to n lu akẹkọọ obinrin naa nilu bara lu sori ayelujara.

Ninu fọnran fidio naa, a ri ọkunrin kan ati awọn obinrin ti wọn n lu obinrin kan.

Fọnran fidio yi mu ki awọn akẹkọ fasiti naa faraya ti wọn si ṣigun lọ ba awọn to hu iwa yi.

Kaakiri loju opo ayelujara lawọn eeyan ti n fi iyalẹnu han lori ohun to le mu ki awọn akẹkọ wọnyi hu iru iwa bẹẹ.

Fasiti FUTA tun ṣalaye pe awọn ṣi n tẹsiwaju pẹlu iwadi lori iṣẹlẹ naa ati pe awọn yoo fi ijiya to le jẹ awọn ti o ba jẹbi ninu iṣẹlẹ ọhun.

Adegbenro Adebanjo sọ pe awọn n ṣe itọju fun akẹkọọ ti wọn lu ninu fọnran fidio naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: